KRONIKA KINNI 7
7
Àwọn Ìran Isakari
1Àwọn mẹrin ni ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu ati Ṣimironi.
2Àwọn ọmọ Tola ni: Usi, Refaaya, Jerieli, Jahimai, Ibisamu ati Ṣemueli, àwọn ni baálé ninu ìdílé Tola, baba wọn, akikanju jagunjagun ni wọ́n ní àkókò wọn. Ní ayé Dafidi ọba, àwọn akikanju jagunjagun wọnyi jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé ẹgbẹta (22,600).
3Usi ni ó bí Isiraya. Isiraya sì bí ọmọ mẹrin: Mikaeli, Ọbadaya, Joẹli, ati Iṣaya; wọ́n di marun-un, àwọn maraarun ni wọ́n sì jẹ́ ìjòyè. 4Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé ìdílé, àwọn jagunjagun tí wọ́n ní tó ẹgbaa mejidinlogun (36,000) kún ara wọn, ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí; nítorí wọ́n ní ọpọlọpọ iyawo ati ọmọ.
5Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu àwọn ìbátan wọn ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogoji ó lé ẹgbẹrun (87,000).
Àwọn Ìran Bẹnjamini ati Dani
6Àwọn mẹta ni ọmọ Bẹnjamini: Bela, Bekeri, ati Jediaeli.
7Bela bí ọmọ marun-un: Esiboni, Usi, Usieli, Jerimotu ati Iri. Àwọn ni baálé ìdílé wọn, wọ́n sì jẹ́ akọni jagunjagun. Gbogbo àwọn akikanju jagunjagun tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ninu ìdílé wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ati mẹrinlelọgbọn (22,034).
8Bekeri bí ọmọ mẹsan-an: Semira, Joaṣi, ati Elieseri; Elioenai, Omiri, ati Jeremotu; Abija, Anatoti, ati Alemeti. 9Àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé, àwọn baálé baálé ní ilé baba wọn, tí wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati igba (20,200). 10Jediaeli ni baba Bilihani; Bilihani bí ọmọ meje: Jeuṣi, Bẹnjamini, Ehudu, Kenaana, Setani, Taṣiṣi ati Ahiṣahari. 11Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jediaeli; àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé ní ilé baba wọn ati akọni jagunjagun ninu ìran wọn tó ẹẹdẹgbaasan-an ó lé igba (17,200). 12Ṣupimu ati Hupimu jẹ́ ọmọ Iri, ọmọ Aheri sì ni Huṣimu.
Àwọn Ìran Nafutali
13Nafutali bí ọmọ mẹrin: Jasieli, Guni, Jeseri, ati Ṣalumu. Biliha ni ìyá baba wọn.
Àwọn Ìran Manase
14Manase fẹ́ obinrin kan, ará Aramea; ọmọ meji ni obinrin náà bí fún un; Asirieli, ati Makiri, baba Gileadi. 15Makiri fẹ́ iyawo kan ará Hupi, ati ọ̀kan ará Ṣupimu. Orúkọ arabinrin rẹ̀ ni Maaka. Orúkọ ọmọ rẹ̀ keji ni Selofehadi; tí gbogbo ọmọ tirẹ̀ jẹ́ kìkì obinrin.
16Maaka, Iyawo Makiri, bí ọmọ meji: Pereṣi ati Ṣereṣi. Ṣereṣi ni ó bí Ulamu ati Rakemu; 17Ulamu sì bí Bedani. Àwọn ni ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase. 18Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila. 19Ṣemida bí ọmọkunrin mẹrin: Ahiani, Ṣekemu, Liki, ati Aniamu.
Àwọn Ìran Efuraimu
20Àwọn arọmọdọmọ Efuraimu nìwọ̀nyí: Ṣutela ni baba Beredi, baba Tahati, baba Eleada, baba Tahati, 21baba Sabadi, baba Ṣutela, Eseri, ati Eleadi; Eseri ati Eleadi yìí ni àwọn ará ìlú Gati pa nígbà tí wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn àwọn ará Gati. 22Baba wọn, Efuraimu, ṣọ̀fọ̀ wọn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá wá láti tù ú ninu. 23Lẹ́yìn náà, Efuraimu bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọmọ náà ní Beraya nítorí ibi tí ó dé bá ìdílé wọn.
24Efuraimu ní ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣeera, òun ló kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati ti ìsàlẹ̀, ati Useni Ṣeera. 25Orúkọ àwọn ọmọ ati arọmọdọmọ Efuraimu yòókù ni Refa, baba Reṣefu, baba Tela, baba Tahani; 26baba Ladani, baba Amihudu, baba Eliṣama; 27baba Nuni, baba Joṣua.
28Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn.
29Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká.
Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé.
Àwọn Ìran Aṣeri
30Àwọn ọmọ Aṣeri nìwọ̀nyí: Imina, Iṣifa, Iṣifi ati Beraya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Sera.
31Beraya bí ọmọkunrin meji: Heberi ati Malikieli, baba Birisaiti.
32Heberi bí ọmọkunrin mẹta: Jafileti, Ṣomeri ati Hotamu; ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣua.
33Jafileti bí ọmọ mẹta: Pasaki, Bimihali, ati Aṣifatu.
34Ṣomeri, arakunrin Jafileti, bí ọmọkunrin mẹta: Roga, Jehuba ati Aramu.
35Hotamu, arakunrin rẹ̀, bí ọmọkunrin mẹrin: Sofa, Imina, Ṣeleṣi ati Amali.
36Sofa bí Ṣua, Haneferi, ati Ṣuali; Beri, ati Imira; 37Beseri, Hodi, ati Ṣama, Ṣiliṣa, Itirani, ati Beera.
38Jeteri bí: Jefune, Pisipa, ati Ara. 39Ula bí: Ara, Hanieli ati Risia.
40Àwọn ni ìran Aṣeri, wọ́n jẹ́ baálé baálé ni ìdílé baba wọn, àṣàyàn akọni jagunjagun, ati olórí láàrin àwọn ìjòyè. Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n tó ogun jà ninu wọn, ní ìdílé ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtala (26,000).
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KINNI 7: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010