KRONIKA KINNI 6

6
Ìran Àwọn Olórí Alufaa
1Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: Geṣomu, Kohati ati Merari.
2Kohati bí ọmọkunrin mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli.
3Amramu bí ọmọ mẹta: Aaroni, Mose, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Miriamu.
Aaroni bí ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.
4Ìran Eleasari ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Eleasari ni baba Finehasi, Finehasi ni ó bí Abiṣua; 5Abiṣua bí Buki, Buki sì bí Usi. 6Usi ni baba Serahaya, Serahaya ló bí Meraiotu, 7Meraiotu bí Amaraya, Amaraya sì bí Ahitubu. 8Ahitubu ni baba Sadoku, Sadoku bí Ahimaasi, 9Ahimaasi bí Asaraya, Asaraya sì bí Johanani. 10Johanani bí Asaraya (òun ni alufaa tí ó wà ninu tẹmpili tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu). 11Asaraya ni baba Amaraya, Amaraya ni ó bí Ahitubu; 12Ahitubu bí Sadoku, Sadoku sì bí Ṣalumu. 13Ṣalumu ni baba Hilikaya; Hilikaya bí Asaraya, 14Asaraya bí Seraaya; Seraaya sì bí Jehosadaki. 15Jehosadaki lọ sí ìgbèkùn nígbà tí Ọlọrun jẹ́ kí Nebukadinesari wá kó Juda ati Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.
Àwọn Ìran Lefi Yòókù
16Àwọn ọmọ Lefi ni: Geriṣoni, Kohati ati Merari. 17Àwọn ọmọ Geriṣoni ni: Libini ati Ṣimei. 18Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli. 19Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili ati Muṣi. Àwọn ni baba ńlá àwọn ọmọ Lefi.#Eks 6:16-19
20Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Geriṣoni nìwọ̀nyí: Libini ni baba Jahati, Jahati bí Sima, 21Sima bí Joa, Joa bí Ido, Ido bí Sera, Sera sì bí, Jeaterai.
22Àwọn tí ó ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kohati nìwọ̀nyí: Aminadabu ni baba Kora, Kora ló bí Asiri; 23Asiri bí Elikana, Elikana bí Ebiasafu, Ebiasafu sì bí Asiri. 24Asiri ni baba Tahati, Tahati ló bí Urieli, Urieli bí Usaya, Usaya sì bí Saulu. 25Ọmọ meji ni Elikana bí: Amasai ati Ahimotu. 26Àwọn ọmọ Ahimotu nìwọ̀nyí: Elikana ni baba Sofai, Sofai ni ó bí Nahati; 27Nahati bí Eliabu, Eliabu bí Jerohamu, Jerohamu sì bí Elikana.
28Samuẹli bí ọmọkunrin meji: Joẹli ni àkọ́bí, Abija sì ni ikeji.
29Àwọn ọmọ Merari nìwọ̀nyí: Mahili ni baba Libini, Libini bí Ṣimei, 30Ṣimei bí Usali, Usali bí Ṣimea, Ṣimea bí Hagaya, Hagaya sì bí Asaya.
Àwọn Ẹgbẹ́ Akọrin Tẹmpili
31Dafidi fi àwọn wọnyi ṣe alákòóso ẹgbẹ́ akọrin ninu ilé OLUWA lẹ́yìn tí wọn ti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sibẹ; 32àwọn ni wọ́n ń kọ orin ninu Àgọ́ Àjọ títí tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA parí ní Jerusalẹmu; àṣegbà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn. 33Àwọn tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà, pẹlu àwọn ọmọ wọn nìwọ̀nyí:
Ninu ìdílé Kohati: Hemani, akọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli, 34ọmọ Elikana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toa, 35ọmọ Sufu, ọmọ Elikana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai, 36ọmọ Elikana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asaraya, ọmọ Sefanaya, 37ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, 38ọmọ Iṣari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli.
39Asafu, arakunrin rẹ̀, ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá ọ̀tun rẹ̀. Asafu yìí jẹ́ ọmọ Berekaya, ọmọ Ṣimea; 40Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseaya, ọmọ Malikija, 41ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaya; 42ọmọ Etani, ọmọ Sima, ọmọ Ṣimei, 43ọmọ Jahati, ọmọ Geriṣomu, ọmọ Lefi.
44Etani arakunrin wọn láti inú ìdílé Merari ni olórí àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ń dúró ní apá òsì rẹ̀. Ìran Etani títí lọ kan Lefi nìyí: ọmọ Kiṣi ni Etani, ọmọ Abidi, ọmọ Maluki; 45ọmọ Haṣabaya, ọmọ Amasaya, ọmọ Hilikaya; 46ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri; 47ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.
48Wọ́n yan àwọn ọmọ Lefi, arakunrin wọn yòókù láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó kù ninu ilé Ọlọrun.
Ìran Aaroni
49Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun ati lórí pẹpẹ turari; àwọn ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn ninu ibi mímọ́ jùlọ, tí wọ́n sì máa ń ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose, iranṣẹ Ọlọrun là sílẹ̀. 50Àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí: Eleasari baba Finehasi, baba Abiṣua; 51baba Buki, baba Usi, baba Serahaya; 52baba Meraiotu, baba Amaraya, baba Ahitubu; 53baba Sadoku, baba Ahimaasi.
Ibi tí Àwọn Ọmọ Lefi Ń Gbé
54Ilẹ̀ tí a pín fún ìran Aaroni nìyí, pẹlu ààlà wọn: ìdílé Kohati ni a kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ninu àwọn ọmọ Lefi. 55Wọ́n fún wọn ní ìlú Heburoni ní ilẹ̀ Juda, ati gbogbo ilẹ̀ pápá oko tí ó yí i ká, 56ṣugbọn Kalebu ọmọ Jefune ni wọ́n fún ní ìgbèríko ati ìletò tí ó yí ìlú Heburoni ká. 57Àwọn ọmọ Aaroni ni a pín àwọn ìlú ààbò wọnyi fún: Heburoni, Libina, Jatiri ati Eṣitemoa, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká. 58Bẹ́ẹ̀ náà ni Hileni, ati Debiri, 59ati Aṣani ati Beti Ṣemeṣi pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. 60Àwọn ìlú tí wọ́n pín fún wọn, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini nìwọ̀nyí: Geba, Alemeti, ati Anatoti, pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. Gbogbo àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní gbogbo ìdílé wọn jẹ́ mẹtala. 61Gègé ni wọ́n ṣẹ́ lórí ìlú mẹ́wàá ara ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, tí wọn sì pín wọn fún àwọn ìdílé Kohati tí ó kù.
62Ìlú mẹtala ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Geriṣomu ní ìdílé ìdílé lára àwọn ìlú ẹ̀yà Isakari, Aṣeri, Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Baṣani. 63Ìlú mejila ni wọ́n pín fún àwọn ọmọ Merari ní ìdílé ìdílé, lára àwọn ìlú ẹ̀yà Reubẹni, Gadi ati ti Sebuluni. 64Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo àwọn ìlú ńláńlá pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká. 65Wọ́n tún ṣẹ́ gègé láti fún wọn ní àwọn ìlú ńláńlá tí a dárúkọ wọnyi lára ìlú àwọn ẹ̀yà Juda, Simeoni ati ti Bẹnjamini.
66Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti pín àwọn ìlú ńláńlá fún àwọn ìdílé kan ninu àwọn ọmọ Kohati. 67Àwọn ìlú ààbò tí wọ́n fún wọn, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká, ní agbègbè olókè Efuraimu nìwọ̀nyí; Ṣekemu, ati Geseri; 68Jokimeamu ati Beti Horoni; 69Aijaloni ati Gati Rimoni. 70Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Kohati tí ó kù ní Aneri ati Bileamu, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
71Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká: Golani ní ilẹ̀ Baṣani, ati Aṣitarotu.
72Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari; wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ati Daberati; 73Ramoti ati Anemu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
74Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní Maṣali ati Abidoni; 75Hukoku ati Rehobu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
76Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Galili, Hamoni, ati Kiriataimu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
77Wọ́n pín àwọn ìlú wọnyi fún àwọn ìdílé tí ó kù ninu àwọn ọmọ Merari.
Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní Rimono ati Tabori, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn. 78Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ní ìkọjá Jọdani níwájú Jẹriko, wọ́n fún wọn ní Beseri tí ó wà ní ara òkè, ati Jahasa, 79Kedemotu ati Mefaati pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.
80Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní Ramoti ní ilẹ̀ Gileadi ati Mahanaimu, 81Heṣiboni ati Jaseri, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 6: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀