KRONIKA KINNI 26

26
Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili
1Bí a ti ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà nìwọ̀nyí: Meṣelemaya, ọmọ Kore, ní ìdílé Asafu, ninu ìran Kora. 2Meṣelemaya bí ọmọ meje, orúkọ wọn nìyí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí wọn, Sakaraya ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Jediaeli, Sebadaya, ati Jatinieli; 3Elamu, Jehohanani ati Eliehoenai.
4Ọmọ mẹjọ ni Obedi Edomu bí nítorí pé Ọlọrun bukun un. Orúkọ àwọn ọmọ náà nìyí, bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí: Ṣemaaya, Jehosabadi, ati Joa; Sakari, ati Netaneli; 5Amieli, Isakari, ati Peuletai.#2Sam 6:11; 1Kron 13:14
6Ṣemaaya, àkọ́bí Obedi Edomu, bí ọmọ mẹfa, àwọn ni olórí ninu ìdílé wọn nítorí pé alágbára eniyan ni wọ́n. 7Orúkọ wọn ni: Otini, Refaeli, Obedi, ati Elisabadi, ati àwọn arakunrin wọn, Elihu ati Semakaya, tí wọ́n jẹ́ alágbára eniyan.
8Gbogbo àwọn arọmọdọmọ Obedi Edomu, ati àwọn ọmọ wọn, pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí wọ́n yẹ láti ṣiṣẹ́ jẹ́ mejilelọgọta.
9Àwọn ọmọ Meṣelemaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí wọ́n lágbára jẹ́ mejidinlogun.
10Hosa, láti inú ìran Merari bí ọmọkunrin mẹrin: Ṣimiri (ni baba rẹ̀ fi ṣe olórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe òun ni àkọ́bí); 11lẹ́yìn rẹ̀ Hilikaya, Tebalaya ati Sakaraya. Gbogbo àwọn ọmọ Hosa ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mẹtala.
12Gbogbo àwọn aṣọ́nà tẹmpili ni a pín sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. A pín iṣẹ́ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí a ti pín iṣẹ́ fún àwọn arakunrin wọn yòókù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA. 13Gègé ni wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan, láti mọ ẹnu ọ̀nà tí wọn yóo máa ṣọ́, wọn ìbáà jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ, wọn ìbáà sì jẹ́ eniyan pataki. 14Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá.
15Obedi Edomu ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà gúsù; àwọn ọmọ rẹ̀ ni a sì yàn láti máa ṣọ́ ilé ìṣúra. 16Gègé mú Ṣupimu ati Hosa fún ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ati ẹnu ọ̀nà Ṣaleketi, ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sí òkè. Olukuluku àwọn aṣọ́nà ni ó ní àkókò iṣẹ́ tirẹ̀. 17Àwọn eniyan mẹfa ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìwọ̀ oòrùn ní ojoojumọ, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà àríwá, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ìhà gúsù, àwọn meji meji sì ń ṣọ́ ilé ìṣúra. 18Fún àgọ́ tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹrin ń ṣọ́ ojú ọ̀nà, àwọn meji sì ń ṣọ́ àgọ́ alára. 19Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn aṣọ́nà láti inú ìran Kora ati ti Merari.
Àwọn Iṣẹ́ Mìíràn ninu Tẹmpili
20Ahija, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ibi tí wọn ń kó àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun sí. 21Ladani, ọ̀kan ninu ìran Geriṣoni, ní àwọn ọmọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé wọn, ọ̀kan ninu wọn ń jẹ́ Jehieli. 22Àwọn ọmọ Jehieli meji: Setamu ati Joẹli ni wọ́n ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.
23A pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Amramu, ati àwọn ọmọ Iṣari, ati àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli.
24Ṣebueli, ọmọ Geriṣomu, láti inú ìran Mose, ni olórí àwọn tí ń bojútó ibi ìṣúra.
25Ninu àwọn arakunrin Ṣebueli, láti ìdílé Elieseri, a yan Rehabaya ọmọ Elieseri, Jeṣaaya ọmọ Rehabaya, Joramu ọmọ Jeṣaaya, Sikiri ọmọ Joramu ati Ṣelomiti ọmọ Sikiri. 26Ṣelomiti yìí ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń bojútó àwọn ẹ̀bùn tí Dafidi ọba, ati ti àwọn olórí àwọn ìdílé, ati èyí tí àwọn olórí ọmọ ogun ẹgbẹẹgbẹrun ati ọgọọgọrun-un, ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun. 27Ninu àwọn ìkógun tí wọ́n kó lójú ogun, wọ́n ya àwọn ẹ̀bùn kan sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú ilé OLUWA. 28Ṣelomiti ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ẹ̀bùn tí àwọn eniyan bá mú wá, ati àwọn ohun tí wolii Samuẹli, ati Saulu ọba, ati Abineri, ọmọ Neri, ati Joabu, ọmọ Seruaya, ti yà sọ́tọ̀ ninu ilé OLUWA.
Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù
29Ninu ìdílé Iṣari, Kenanaya ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n yàn ní alákòóso ati onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli.
30Ninu ìdílé Heburoni, Haṣabaya ati ẹẹdẹgbẹsan (1,700) àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alágbára ni wọ́n ń bojútó àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ OLUWA ati iṣẹ́ ọba, 31Ninu ìdílé Heburoni, Jerija ni baba ńlá gbogbo wọn. (Ní ogoji ọdún tí Dafidi dé orí oyè, wọ́n ṣe ìwádìí nípa ìran Heburoni, wọ́n sì rí àwọn ọkunrin tí wọ́n lágbára ninu ìran wọn ní Jaseri ní agbègbè Gileadi). 32Dafidi ọba, yan òun ati àwọn arakunrin rẹ̀, tí gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa ó lé ẹẹdẹgbẹrin (2,700) alágbára, láti jẹ́ alámòójútó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase nípa gbogbo nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun ati àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ọba.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 26: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀