KRONIKA KINNI 25
25
Àwọn Akọrin Inú Tẹmpili
1Dafidi ati àwọn olórí ogun ya àwọn kan sọ́tọ̀ ninu àwọn ọmọ Asafu, Hemani ati ti Jedutuni láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fi dùùrù, ati hapu ati aro kọrin. Àkọsílẹ̀ àwọn tí a yàn ati iṣẹ́ wọn nìyí:
2Lára àwọn ọmọ Asafu wọ́n yan Sakuri, Josẹfu, Netanaya, ati Asarela; wọ́n wà lábẹ́ àkóso Asafu, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ àkóso ọba.
3Àwọn ọmọ Jedutuni jẹ́ mẹfa: Gedalaya, Seri, ati Jeṣaaya; Ṣimei, Haṣabaya ati Matitaya, abẹ́ àkóso Jedutuni, baba wọn, ni wọ́n wà, wọn a sì máa fi dùùrù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ninu orin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.
4Àwọn ọmọ Hemani ni: Bukaya, Matanaya, Usieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananaya, Hanani, Eliata, Gidaliti, ati Romamiti Eseri, Joṣibekaṣa, Maloti, Hotiri, ati Mahasioti. 5Ọmọ Hemani, aríran ọba, ni gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Ọlọrun ṣe láti gbé Hemani ga; Ọlọrun fún un ní ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta. 6Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń lu aro ati hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù lábẹ́ àkóso baba wọn ninu ìsìn ninu ilé Ọlọrun. Ṣugbọn Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà lábẹ́ àkóso ọba.
7Àpapọ̀ wọn pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí a ti kọ́ ní orin kíkọ sí OLUWA, ati lílo ohun èlò orin, jẹ́ ọọdunrun ó dín mejila (288).
8Gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi mọ iṣẹ́ olukuluku; ati kékeré ati àgbà, ati olùkọ́ ati akẹ́kọ̀ọ́.
9Gègé kinni tí wọ́n ṣẹ́ fún ìdílé Asafu mú Josẹfu; ekeji mú Gedalaya, òun ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ́ mejila. 10Ẹkẹta mú Sakuri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 11Ẹkẹrin mú Isiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 12Ẹkarun-un mú Netanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 13Ẹkẹfa mú Bukaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 14Ekeje mú Jeṣarela, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 15Ẹkẹjọ mú Jeṣaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 16Ẹkẹsan-an mú Matanaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 17Ẹkẹwaa mú Ṣimei, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 18Ikọkanla mú Asareli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 19Ekejila mú Haṣabaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 20Ẹkẹtala mú Ṣubaeli, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 21Ẹkẹrinla mú Matitaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 22Ẹkẹẹdogun mú Jeremotu, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 23Ẹkẹrindinlogun mu Hananaya, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 24Ẹkẹtadinlogun mú Joṣibekaṣa, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 25Ekejidinlogun mú Hanani, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 26Ikọkandinlogun mú Maloti, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 27Gègé ogún mú Eliata, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 28Ikọkanlelogun mú Hotiri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 29Ekejilelogun mú Gidaliti, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 30Ẹkẹtalelogun mú Mahasioti, òun ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila. 31Ẹkẹrinlelogun mú Romamiti Eseri, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati àwọn arakunrin rẹ̀ jẹ́ mejila.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KINNI 25: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: