KRONIKA KINNI 27

27
Àwọn Ológun ati Ètò Òṣèlú
1Àwọn wọnyi ni àwọn olórí ìdílé ati olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati olórí ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ aṣojú ọba ní gbogbo ìpínlẹ̀ ní oṣooṣù, títí ọdún yóo fi yípo ni wọn máa ń yan ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000) eniyan, tí wọn ń pààrọ̀ ara wọn.
2Jaṣobeamu, ọmọ Sabidieli, ni olórí ìpín kinni, fún oṣù kinni; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji. 3Ìran Peresi ni Jaṣobeamu, òun sì ni balogun fún gbogbo àwọn ọ̀gágun fún oṣù kinni. 4Dodai, láti inú ìran Ahohi, ni olórí ìpín ti oṣù keji, iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 5Balogun kẹta, tí ó wà fún oṣù kẹta ni Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, alufaa. Iye àwọn tí ó wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 6Bẹnaya yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọgbọ̀n akọni jagunjagun, òun sì ni olórí wọn. Amisabadi ọmọ rẹ̀ ni ó ń ṣe àkóso ìpín rẹ̀. 7Asaheli, arakunrin Joabu, ni balogun fún oṣù kẹrin. Sebadaya, ọmọ rẹ̀, ni igbákejì rẹ̀. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 8Balogun tí ó wà fún oṣù karun-un ni Ṣamuhutu, láti inú ìran Iṣari; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 9Balogun tí ó wà fún oṣù kẹfa ni Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 10Balogun tí ó wà fún oṣù keje ni Helesi, ará Peloni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 11Balogun tí ó wà fún oṣù kẹjọ ni Sibekai, ará Huṣa, láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 12Balogun tí ó wà fún oṣù kẹsan-an ni Abieseri ará Anatoti, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 13Balogun tí ó wà fún oṣù kẹwaa ni Maharai, ará Netofa láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 14Balogun tí ó wà fún oṣù kọkanla ni Bẹnaya, ará Piratoni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000). 15Balogun tí ó wà fún oṣù kejila ni Helidai ará Netofati, láti inú ìran Otinieli; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
Ètò Àkóso Àwọn Ẹ̀yà Israẹli
16Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí, láti inú ẹ̀yà Reubẹni: Elieseri, ọmọ Sikiri ni olórí patapata. Láti inú ẹ̀yà Simeoni: Ṣefataya, ọmọ Maaka. 17Láti inú ẹ̀yà Lefi: Haṣabaya, ọmọ Kemueli; láti ìdílé Aaroni: Sadoku; 18láti inú ẹ̀yà Juda: Elihu, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi; láti inú ẹ̀yà Isakari: Omiri, ọmọ Mikaeli; 19láti inú ẹ̀yà Sebuluni: Iṣimaya, ọmọ Ọbadaya; láti inú ẹ̀yà Nafutali: Jeremotu, ọmọ Asirieli; 20láti inú ẹ̀yà Efuraimu: Hoṣea, ọmọ Asasaya; láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase: Joẹli, ọmọ Pedaya; 21láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Gileadi: Ido, ọmọ Sakaraya; láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini: Jaasieli, ọmọ Abineri; 22láti inú ẹ̀yà Dani: Asareli, ọmọ Jerohamu. Àwọn ni olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli.
23Dafidi kò ka àwọn tí wọn kò tó ọmọ ogún ọdún, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìlérí pé òun yóo mú kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run. 24Joabu, ọmọ Seruaya, bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn eniyan, ṣugbọn kò parí rẹ̀. Sibẹsibẹ ibinu OLUWA wá sórí Israẹli nítorí rẹ̀; nítorí náà, kò sí àkọsílẹ̀ fún iye àwọn ọmọ Israẹli ninu ìwé ìtàn ọba Dafidi.#Jẹn 15:5; 22:17; 26:4 #2Sam 24:15; 1Kron 21:1-14
25Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́. 26Esiri, ọmọ Kelubu, ni alabojuto fún gbogbo iṣẹ́ oko dídá. 27Ṣimei, ará Rama, ni ó wà fún àwọn ọgbà àjàrà. Sabidi, ará Ṣifimu, ni ó wà fún ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí. 28Baali Hanani, ará Gederi, ni ó wà fún àwọn ọgbà olifi ati ti igi sikamore. Joaṣi ni ó wà fún ibi tí wọ́n ń kó òróró olifi pamọ́ sí. 29Ṣitirai, ará Ṣaroni, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní Ṣaroni. Ṣafati, ọmọ Adila, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní àwọn àfonífojì. 30Obili, ará Iṣmaeli, ni ó wà fún àwọn ràkúnmí. Jedeaya, ará Meronoti, ni ó wà fún àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jasisi, ará Hagiri, sì jẹ́ alabojuto àwọn agbo aguntan. 31Gbogbo wọn jẹ́ alabojuto àwọn ohun ìní Dafidi ọba.
Àwọn Olùdámọ̀ràn Dafidi Ọba
32Jonatani, arakunrin baba Dafidi ọba, ni olùdámọ̀ràn nítorí pé ó ní òye, ó sì tún jẹ́ akọ̀wé. Òun ati Jehieli, ọmọ Hakimoni, ní ń ṣe àmójútó àwọn ọmọ ọba. 33Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn fún ọba, Huṣai ará Ariki sì ni ọ̀rẹ́ ọba. 34Lẹ́yìn ikú Ahitofeli, Jehoiada, ọmọ Bẹnaya ati Abiatari di olùdámọ̀ràn ọba. Joabu sì jẹ́ balogun ọba.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 27: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀