Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Owe 4:23

Irin-ìdáàbòbò: Yíyẹra fún Àbámọ̀ ní Ìgbésí-ayé Rẹ
Ọjọ́ márùn-ún
A máa fi irin í dáàbò ojú pópó síbè fún ààbò ọkọ̀ kí wọn má bàa yapa sì ibi tí ó lewu tàbí ibi tí kò yẹ kí wọn rìn sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a kì í rí wọn títí ao fi nílò wọn - nígbà náà, a ó ṣọpé pe wọn wa níbè. Báwo ni ìbá tí rí bí a bá ní iru irin í dáàbò bayi ninu àjọṣe wá, ìdọ́kòwò wá, àti isé wá? Báwo ni wọn yóò rí? Kí ni wọn ṣe lè pá wá mọ kúrò lọ́wọ́ ìkábàmọ̀? Fún ìwọ̀n ojo márùn-ún láti òní, ẹ jẹ ki a gbe bí a ṣe lè fi irú irin í dáàbò bayi sì ayé wa yẹ̀ wò.

Tún Ọkàn Rẹ Tò: Ọjọ́ 10 Láti Ba Ẹ̀ṣẹ̀ Jà
Ọjọ́ 10
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni gbàgbọ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti borí ẹ̀ṣẹ̀ ni láti fi ara mọ́-ọn kí a sì má ṣubú sí inú ìdánwò. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè fi ọkàn rẹ ja ẹ̀ṣẹ̀; o gbọ́dọ̀ fi ọkàn rẹ jà á. Ètò ọjọ́ mẹ́wàá yìí da l'órí ìwé Rewire Your Heart, ó sì wo díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ tí ó pàtàkì jù lọ nípa ọkàn rẹ tí yoo ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti ṣe àwárí bí o ṣe lè k'ojú ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígba Ìhìnrere ní ààyè láti tún ọkàn rẹ ṣe.
