← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Joh 4:14

Bí A (Kò) Ṣe Lè Gba Ayé Là: Òtítọ́ Nípa Fífi Ìfẹ́ Ọlọ́run Hàn Sí Àwọn Ènìyàn Tí Ó Wà Ní Ẹ̀gbẹ́ẹ̀ Rẹ
Ọjọ́ 5
Ṣé o fẹ́ jà fún àwọn ènìyàn tí o fẹ́ràn kí o sì fi han àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe ní iye l'órí tó sí Ọlọ́run? Nínú ètò kíkà ọlọ́jọ́ 5 yìí, tí ó dá l'órí ìwé Hosanna Wong How (Not) to Save the World, ṣe àwárí àwọn irọ́ tí ó ń dí ọ l'ọ́wọ́ l'áti ní ìfẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí Ọlọ́run ṣe pè ọ́ sí. Gba àkókò l'áti ṣe àwárí ìfìwépè Jésù l'áti mọ̀ On, kí o pín-In pẹ̀lú áwọn ẹlòmíràn nípasẹ ìrírí aláìlẹ́gbẹ́ rẹ.

Ìgboyà
Ọ̀sẹ̀ kan
Kọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgboyà. Ètò kíkà “Ìgboyà” rán àwọn onígbàgbọ́ létí ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú Kristi àti nínú ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí a bá jẹ́ ti Ọlọrun, a ní òmìnira láti súnmọ́-On tààrà. Kà lẹ́ẹ̀kansi - tàbí bóyá fún ìgbà àkọ́kọ́ - àwọn ìdánilójú pé ipò rẹ nínú ìdílé Ọlọrun wà síbẹ̀.