YouVersion Logo
Search Icon

JOẸLI 1

1
1Iṣẹ́ tí OLUWA rán Joẹli, ọmọ Petueli nìyí:
Ìdárò nítorí Ìparun Nǹkan Ọ̀gbìn
2Ẹ gbọ́, ẹ̀yin àgbà,
ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí!
Ǹjẹ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ rí ní àkókò yín,
tabi ní àkókò àwọn baba yín?
3Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín nípa rẹ̀,
kí àwọn náà sọ fún àwọn ọmọ wọn,
kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún àwọn ọmọ tiwọn náà.
4Ohun tí eṣú wẹẹrẹ jẹ kù,
ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ ẹ́.
Èyí tí ọ̀wọ́ àwọn eṣú ńláńlá jẹ kù,
àwọn eṣú wẹẹrẹ mìíràn jẹ ẹ́,
èyí tí àwọn eṣú wẹẹrẹ yìí jẹ kù,
àwọn eṣú tí ń jẹ nǹkan run jẹ ẹ́ tán.
5Ẹ jí lójú oorun, ẹ̀yin ọ̀mùtí,
ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń mu waini,
nítorí waini tuntun tí a já gbà kúrò lẹ́nu yín.
6Orílẹ̀-èdè kan ti dojú kọ ilẹ̀ mi,
wọ́n lágbára, wọ́n pọ̀, wọn kò sì lóǹkà;
eyín wọn dàbí ti kinniun.
Ọ̀gàn wọn sì dàbí ti abo kinniun.#Ifi 9:8
7Wọ́n ti run ọgbà àjàrà mi,
wọ́n ti já àwọn ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi,
wọ́n ti bó gbogbo èèpo ara rẹ̀,
wọ́n ti wó o lulẹ̀,
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ti di funfun.
8Ẹ sọkún bí ọmọge tí ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,
nítorí ikú àfẹ́sọ́nà ìgbà èwe rẹ̀.
9A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA,
àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀.
10Ilẹ̀ ti gbẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀,
nítorí a ti run ọkà, àjàrà ti tán, epo olifi sì ń tán lọ.
11Ẹ banújẹ́, ẹ̀yin àgbẹ̀,
ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ẹ̀yin tí ẹ̀ ń tọ́jú ọgbà àjàrà,
nítorí ọkà alikama ati ọkà baali,
ati nítorí pé ohun ọ̀gbìn ti ṣègbé.
12Èso àjàrà ti rọ,
igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti ń gbẹ.
Igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ ati igi ápù, ati gbogbo àwọn igi eléso ti gbẹ,
inú ọmọ eniyan kò sì dùn mọ́.
13Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa,
ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,
ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ.
Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé,
kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn,
nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.
14Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ.
Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín,
kí ẹ sì kígbe pe OLUWA.
15Ó ṣe! Ọjọ́ náà ń bọ̀,
ọjọ́ OLUWA dé tán!
Ọjọ́ náà yóo dé bí ọjọ́ ìparun láti ọ̀dọ̀ Olodumare.#Ais 13:6
16A ti gba oúnjẹ lẹ́nu yín, níṣojú yín,
bẹ́ẹ̀ ni a gba ayọ̀ ati inú dídùn kúrò ní ilé Ọlọrun wa.
17Irúgbìn díbàjẹ́ sinu ebè,
àwọn ilé ìṣúra ti di ahoro,
àwọn àká ti wó lulẹ̀,
nítorí kò sí ọkà láti kó sinu wọn mọ́.
18Àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora,
àwọn agbo mààlúù dààmú,
nítorí pé kò sí pápá oko fún wọn;
àwọn agbo aguntan pàápàá dààmú.
19Ìwọ ni mo kígbe pè, OLUWA,
nítorí iná ti jó gbogbo pápá oko run,
ó sì ti jó gbogbo igi oko run.
20Àwọn ẹranko ìgbẹ́ pàápàá ń kígbe sí ọ, Ọlọrun,
nítorí gbogbo àwọn odò ti gbẹ tán,
àwọn pápá oko sì ti jóná.

Currently Selected:

JOẸLI 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy