YouVersion Logo
Search Icon

JOẸLI 2

2
Ọ̀wọ́ Eṣú, gẹ́gẹ́ bí Àmì Ìkéde Ọjọ́ OLUWA
1Ẹ fun fèrè ní Sioni,
ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi.
Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì,
nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán.
2Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́,
ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri.
Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá,
bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀.
Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́,
bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae.
3Iná ń jó àjórun níwájú wọn,
ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn.
Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn,
ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro,
kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn.
4Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin,
wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun.
5Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun,
wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá.
Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá,
bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun.#Ifi 9:7-9
6Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n,
gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì.
7Wọ́n ń sáré bí akọni,
wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun.
Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́,
ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀.
8Wọn kò fi ara gbún ara wọn,
olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀;
wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró.
9Wọ́n ń gun odi ìlú,
wọ́n ń sáré lórí odi.
Wọ́n ń gun orí ilé wọlé,
wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè.
10Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn,
ọ̀run sì ń wárìrì,
oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn.#Ifi 8:12
11OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,
nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ,
alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.
Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA!
Ta ló lè faradà á?#Ifi 6:17
Ìpè fún Ìrònúpìwàdà
12OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii,
pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn,
13Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́,
kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.”
Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín,
nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni.
Kì í yára bínú,
Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,
a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.
14Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada,
kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀,
kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.
15Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni,
ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ.
16Ẹ pe gbogbo eniyan jọ,
kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́.
Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ,
ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.
Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀,
kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.
17Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ.
Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí,
má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé,
‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”#1 Makab 7:36-38
Ọlọrun Yóo Dá Ìbísí Pada sórí Ilẹ̀ náà
18Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,
ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.
19OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,
“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,
ẹ óo ní ànítẹ́rùn.
N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.
20N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín,
n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan.
N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn,
n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn.
Òkú wọn yóo máa rùn;
n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.
21Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀,
jẹ́ kí inú rẹ máa dùn,
kí o sì máa yọ̀,
nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá.
22Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó,
nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù,
igi gbogbo ti so èso,
igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì.
23“Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni,
kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín;
nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò,
ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín:
ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.
24Gbogbo ibi ìpakà ni yóo kún fún ọkà,
ìkòkò waini ati ti òróró yín yóo kún àkúnwọ́sílẹ̀.
25Gbogbo ohun tí ẹ pàdánù
ní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín;
ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ,
gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín.
26Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn,
ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín,
tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín,
ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.
27Ẹ óo mọ̀ pé mo wà láàrin Israẹli;
ati pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín,
kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi mọ́.
Ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.
Ọjọ́ OLUWA
28“Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá,
n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan,
àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin
yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀,
àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá,
àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran.
29Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó,
n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín.
30“Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀,
n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run,
ati sórí ilẹ̀ ayé;
yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín.
31Oòrùn yóo ṣókùnkùn,
òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀,
kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé.#Mat 24:29; Mak 13:24-25; Luk 21:25; Ifi 6:12-13
32Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà.
Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni,
ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ,
àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.#A. Apo 2:17-21 #Rom 10:13

Currently Selected:

JOẸLI 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy