YouVersion Logo
Search Icon

RUTU 3

3
Rutu rí Ọkọ Fẹ́
1Lẹ́yìn náà, Naomi pe Rutu, ó ní, “Ọmọ mi, ó tó àkókò láti wá ọkọ fún ọ, kí ó lè dára fún ọ. 2Ṣé o ranti pé ìbátan wa ni Boasi, tí o wà pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀? Wò ó, yóo lọ fẹ́ ọkà baali ní ibi ìpakà rẹ̀ lálẹ́ òní. 3Nítorí náà, lọ wẹ̀, kí o sì fi nǹkan pa ara. Wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ibi ìpakà rẹ̀, ṣugbọn má jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí ó bá jẹ tí ó sì mu tán. 4Nígbà tí ó bá fẹ́ sùn, ṣe akiyesi ibi tí ó sùn sí dáradára, lẹ́yìn náà, lọ ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì sùn tì í, lẹ́yìn náà, yóo sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.”
5Rutu bá dá Naomi lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni n óo ṣe.”
6Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un. 7Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í. 8Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, Boasi tají lójijì, bí ó ti yí ara pada, ó rí i pé obinrin kan sùn ní ibi ẹsẹ̀ òun. 9Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?”
Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.”
10Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka. 11Má bẹ̀rù, ọmọ mi, gbogbo ohun tí o bèèrè ni n óo ṣe fún ọ, nítorí pé gbogbo àwọn ọkunrin ẹlẹgbẹ́ mi ní ilẹ̀ yìí ni wọ́n mọ̀ pé obinrin gidi ni ọ́. 12Òtítọ́ ni mo jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ rẹ, ṣugbọn ẹnìkan wà tí ó tún súnmọ́ ọn jù mí lọ. 13Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.”#Rut 2:20
14Rutu bá sùn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ṣugbọn ó tètè dìde ní àfẹ̀mọ́jú, kí eniyan tó lè dá eniyan mọ̀. Boasi bá kìlọ̀ fún un pé, “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ pé o wá sí ibi ìpakà.” 15Boasi sọ fún un pe kí ó tẹ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, kí ó sì fi ọwọ́ mú un, Rutu náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Boasi wọn ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa sinu aṣọ náà, ó dì í, ó gbé e ru Rutu, Rutu sì pada sí ilé. 16Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ bi í pé, “Báwo ni ibẹ̀ ti rí, ọmọ mi?”
Rutu bá sọ gbogbo ohun tí ọkunrin náà ṣe fún un. 17Ó ní, “Ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa ni ó dì fún mi, nítorí ó sọ pé n kò gbọdọ̀ pada sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ mi ní ọwọ́ òfo.”
18Naomi bá dáhùn, ó ní, “Fara balẹ̀ ọmọ mi, títí tí o óo fi gbọ́ bí ọ̀rọ̀ náà yóo ti yọrí sí; nítorí pé ara ọkunrin yìí kò ní balẹ̀ títí tí yóo fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”

Currently Selected:

RUTU 3: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy