YouVersion Logo
Search Icon

ROMU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Nítorí ati ṣánnà fún ìbẹ̀wò tí Paulu fẹ́ lọ ṣe sí ìjọ tí ó wà ní Romu, ni ó mú un kọ ìwé tí à ń pè ní Ìwé sí Àwọn Ará Romu. Èrò rẹ̀ ni pé òun óo ṣiṣẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, pẹlu àtìlẹ́yìn wọn, òun óo lọ sí Spania. Ó kọ ìwé sí wọn láti ṣe àlàyé lórí irú òye tí ó ní nípa ẹ̀sìn igbagbọ ati irú àyọrísí tí ó yẹ kí ẹ̀sìn yìí ní ninu ìgbé-ayé onigbagbọ. Ninu ìwé yìí ni Paulu ti ṣe àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ jùlọ nípa iṣẹ́ tí ó níláti jẹ́.
Lẹ́yìn tí Paulu ti kí àwọn eniyan inú ìjọ ní Romu tí ó sì sọ fún wọn nípa bí ó ṣe ń gbadura fún wọn, ó sọ ohun tí ó jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí wọn pé: ìyìn rere fihàn wá bí Ọlọrun ti ṣe mú kí nǹkan dọ́gba láàrin àwọn eniyan ati ara rẹ̀. Igbagbọ ni okùnfà ìdọ́gba yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin (1:17).
Lẹ́yìn náà, Paulu bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀rọ̀ yìí pé: ati Juu ni, ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni, gbogbo eniyan ló yẹ kí ààrin àwọn ati Ọlọrun dọ́gba, nítorí pé bákan náà ni gbogbo wọn jọ wà lábẹ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀. Igbagbọ ninu Jesu ni ó ń mú ìdọ́gba wá láàrin Ọlọrun ati eniyan. Ohun tí Paulu tún mẹ́nubà lẹ́yìn èyí ni àlàyé lórí ìgbé-ayé titun tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Jesu, tí àwọn onigbagbọ máa ń ní, nítorí pé nǹkan dọ́gba láàrin àwọn ati Ọlọrun. Onigbagbọ ní alaafia pẹlu Ọlọrun, ẹ̀mí Ọlọrun sì fún un ní ìdáǹdè kúrò ninu agbára ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ikú. Ninu orí karun-un títí dé orí kẹjọ, Paulu ṣe àlàyé lórí ohun tí Òfin wà fún, ati agbára Ẹ̀mí Ọlọrun ninu ìgbé-ayé onigbagbọ. Lẹ́yìn èyí Paulu gbìyànjú láti ṣe àlàyé lórí ààyè tí àwọn Juu ati àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn wà ninu ètò Ọlọrun fún gbogbo eniyan. Ohun tí ó fi ká àlàyé rẹ̀ lẹ́sẹ̀ ni pé, kíkọ̀ tí àwọn Juu kọ Jesu jẹ́ ara ètò Ọlọrun láti mú oore-ọ̀fẹ́ Jesu wá sí àrọ́wọ́tó gbogbo eniyan. Ó gbàgbọ́ pé kíkọ̀ tí àwọn Juu kọ Jesu kì í ṣe ọ̀rọ̀ títí laelae. Ní ìparí, Paulu sọ̀rọ̀ lórí irú ìgbé-ayé tí ó yẹ kí onigbagbọ máa gbé, pataki jùlọ nípa bí ó ti yẹ láti fi ìfẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn lò. Ó tún mẹ́nuba àwọn kókó ọ̀rọ̀ iṣẹ́ onigbagbọ sí Ọlọrun, sí ìjọba, ati sí àwọn ẹlòmíràn. Ó sì tún mẹ́nuba ọ̀rọ̀ ẹ̀rí-ọkàn pẹlu. Ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́ ati ìyìn Ọlọrun ni ó fi kásẹ̀ ìwé náà nílẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju ati kókó ọ̀rọ̀ ìwé náà 1:1-17
Bí eniyan ṣe nílò ìgbàlà 1:18–3:20
Ọ̀nà tí Ọlọrun là sílẹ̀ fún ìgbàlà 3:21–4:25
Ìgbé-ayé titun ninu Kristi 5:1–8:39
Israẹli ninu ètò Ọlọrun 9:1–11:36
Ìwà onigbagbọ 12:1–15:13
Ọ̀rọ̀ ìparí ati ìkíni 15:14–16:27

Currently Selected:

ROMU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy