YouVersion Logo
Search Icon

ÌWÉ ÒWE 31

31
Ìmọ̀ràn fún Ọba
1Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ:
2Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi,
ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí.
3Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin,
má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́.
4Gbọ́, ìwọ Lemueli,
ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí,
àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle.
5Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin,
kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po.
6Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu,
fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle,
7jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn,
kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́.
8Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò,
ati ti àwọn tí a sọ di aláìní.
9Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,
bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn.
Iyawo tí Ó Ní Ìwà Rere
10Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́?
Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ.
11Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e,
kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun.
12Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un
kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ,
a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ.
14Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,
tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.
15Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,
ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.
16Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,
a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.
17A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,
a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.
18A máa mójútó ọjà tí ó ń tà,
fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru.
19Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú,
ó sì ń ran òwú.
20Ó lawọ́ sí àwọn talaka,
a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́.
21Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù,
nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru.
22A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀,
òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò.
23Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè,
nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú.
24A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n,
a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.
25Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ,
ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú.
26Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀,
a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú.
27A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára,
kì í sì í hùwà ọ̀lẹ.
28Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun,
ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé,
29“Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi,
ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”
30Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà,
obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn.
31Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,
jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Currently Selected:

ÌWÉ ÒWE 31: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy