YouVersion Logo
Search Icon

JAKỌBU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé láti Ọ̀dọ̀ Jakọbu jẹ́ àkójọ oríṣìíríṣìí ìlànà ati ẹ̀kọ́ tí a kọ “sí gbogbo eniyan Ọlọrun tí ó fọ́n káàkiri gbogbo ayé.” Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ àpèjúwe tí ó múni lọ́kàn ni ẹni tí ó kọ ìwé yìí lò láti gbé ìlànà rẹ̀ kalẹ̀ nípa ọgbọ́n tí ó ṣe é múlò ati ìtọ́ni fún ìhùwàsí ati ìṣe onigbagbọ. Ọpọlọpọ kókó ọ̀rọ̀ ni ó mẹ́nubà, ó sì sọ ìhà tí onigbagbọ níláti kọ sí àwọn nǹkan bí ọrọ̀, àìní, ìdánwò, ìwà rere, igbagbọ ati iṣẹ́, fífi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ọgbọ́n, ìjà, ìgbéraga ati ìrẹ̀lẹ̀; dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnu fífọ́n, sùúrù ati adura.
Ìwé yìí tẹnumọ́ ọn pé ó ṣe pataki pé kí iṣẹ́ kún igbagbọ ninu mímú ẹ̀sìn igbagbọ lò.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju 1:1
Igbagbọ ati ọgbọ́n 1:2-8
Àìní ati ọrọ̀ 1:9-11
Ìdẹwò ati ìdánwò 1:12-18
Gbígbọ́ ati ṣíṣe 1:19-27
Ìkìlọ̀ nípa yíya àwọn kan sọ́tọ̀ 2:1-13
Igbagbọ ati iṣẹ́ 2:14-26
Onigbagbọ ati ahọ́n rẹ̀ 3:1-18
Onigbagbọ ati ayé 4:1–5:6
Oríṣìíríṣìí ìlànà 5:7-20

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy