YouVersion Logo
Search Icon

DIUTARONOMI 2

2
1“Nígbà tí ó yá, a pada sinu aṣálẹ̀ ní ọ̀nà Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi; a sì rìn káàkiri lórí òkè Seiri fún ọpọlọpọ ọjọ́. #Nọm 21:4
2“OLUWA bá wí fún mi pé, 3‘Ìrìn tí ẹ rìn káàkiri ní agbègbè olókè yìí tó gẹ́ẹ́; ẹ yipada sí apá àríwá.’ 4OLUWA ní kí n pàṣẹ pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ óo là kọjá yìí jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Esau, àwọn arakunrin yín, tí wọn ń gbé òkè Seiri. Ẹ̀rù yín yóo máa bà wọ́n, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi; 5ẹ má bá wọn jà, nítorí n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí ó kéré tó. Mo ti fi gbogbo ilẹ̀ Edomu ní òkè Seiri fún arọmọdọmọ Esau, gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. 6Ẹ óo ra oúnjẹ jẹ lọ́wọ́ wọn, ẹ óo sì ra omi mu lọ́wọ́ wọn.’ #Jẹn 36:8
7“Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.
8“A bá kọjá lọ láàrin àwọn arakunrin wa, àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri, a ya ọ̀nà tí ó lọ láti Elati ati Esiongeberi sí Araba sílẹ̀. A yipada a sì gba ọ̀nà aṣálẹ̀ Moabu. 9OLUWA sọ fún mi pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ da àwọn ará Moabu láàmú, tabi kí ẹ gbógun tì wọ́n; nítorí pé n kò fun yín ní ilẹ̀ wọn, nítorí pé mo ti fi ilẹ̀ Ari fún àwọn ọmọ Lọti gẹ́gẹ́ bí ohun ìní wọn.’ ” #Jẹn 19:37
10(Ìran àwọn òmìrán kan tí à ń pè ní Emimu ní ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Wọ́n pọ̀, wọ́n sì lágbára. Wọ́n ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki. 11Wọn a máa pè wọ́n ní Refaimu gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Anakimu, ṣugbọn àwọn ará Moabu ń pè wọ́n ní Emimu. 12Àwọn ará Hori ni wọ́n ń gbé òkè Seiri tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn ọmọ Esau ti gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti pa wọ́n run. Wọ́n bá tẹ̀dó sórí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hori gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli náà ti tẹ̀dó sórí ilẹ̀ tí wọ́n gbà, tí OLUWA fún wọn.)
13“Ẹ dìde nisinsinyii kí ẹ sì kọjá sí òdìkejì odò Seredi. A sì ṣí lọ sí òdìkejì odò Seredi. 14Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí. 15OLUWA dójúlé wọn nítòótọ́ títí gbogbo wọn fi parun patapata ninu ibùdó àwọn ọmọ Israẹli. #Nọm 14:28-35
16“Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun-ún jà ti kú tán láàrin àwọn ọmọ Israẹli, 17OLUWA bá wí fún mi pé, 18‘Òní ni ọjọ́ tí ẹ óo ré ààlà àwọn ará Moabu kọjá ní Ari. 19Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni, ẹ má ṣe dà wọ́n láàmú, ẹ má sì bá wọn jagun, nítorí pé n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, nítorí pé, àwọn ọmọ Lọti ni mo ti fún.’ ” #Jẹn 19:38
20(Ibẹ̀ ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ Refaimu, nítorí pé, àwọn Refaimu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn ará Amoni a máa pè wọ́n ní Samsumimu. 21Àwọn tí à ń pè ní Refaimu yìí pọ̀, wọ́n lágbára, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki, àwọn òmìrán. Ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run fún àwọn ará Amoni, wọ́n gba ilẹ̀ wọn, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ. 22Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run fún wọn, tí àwọn ọmọ Esau gba ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ títí di òní olónìí, ni ó ṣe fún àwọn ará Amoni. 23Àwọn ará Afimu ni wọ́n ti ń gbé àwọn ìletò tí wọ́n wà títí dé Gasa tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn àwọn kan tí wọ́n wá láti Kafitori ni wọ́n pa wọ́n run, tí wọ́n sì tẹ̀dó sí ilẹ̀ wọn.)
24“Ẹ dìde, ẹ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yín, kí ẹ sì ré àfonífojì Anoni kọjá. Mo ti fi Sihoni, ọba Heṣiboni, ní ilẹ̀ àwọn ará Amori, le yín lọ́wọ́, àtòun ati ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bá a jagun, kí ẹ sì máa gba ilẹ̀ rẹ̀. 25Láti òní lọ, n óo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé yìí, tí wọ́n bá gbúròó yín, wọn yóo máa gbọ̀n, ojora yóo sì mú wọn nítorí yín.
Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣẹgun Sihoni Ọba
(Nọm 21:21-30)
26“Nítorí náà mo rán àwọn oníṣẹ́ láti aṣálẹ̀ Kedemotu, sí Sihoni, ọba Heṣiboni. Iṣẹ́ alaafia ni mo rán sí i, mo ní, 27‘Jẹ́ kí n kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ. Ojú ọ̀nà tààrà ni n óo máa gbà lọ. N kò ní yà sí ọ̀tún tabi sí òsì. 28Rírà ni n óo ra oúnjẹ tí n óo jẹ lọ́wọ́ rẹ, n óo sì ra omi tí n óo mu pẹlu. Ṣá ti gbà mí láàyè kí n kọjá, 29bí àwọn ọmọ Esau, tí wọn ń gbé Seiri ati àwọn ará Moabu tí wọn ń gbé Ari, ti ṣe fún mi, títí tí n óo fi kọjá odò Jọdani, lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wa ti fi fún wa.’
30“Ṣugbọn Sihoni, ọba Heṣiboni kọ̀ fún wa, kò jẹ́ kí á kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí OLUWA Ọlọrun yín mú kí ọkàn rẹ̀ le, ó sì mú kí ó ṣe oríkunkun, kí ó lè fi le yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe lónìí.
31“OLUWA sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí fi Sihoni ati ilẹ̀ rẹ̀ le yín lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí gbà á, kí ẹ lè máa gbé ibẹ̀.’ 32Sihoni bá jáde sí wa, òun ati àwọn eniyan rẹ̀, láti bá wa jagun ní Jahasi. 33OLUWA Ọlọrun wa fi lé wa lọ́wọ́, a ṣẹgun rẹ̀, ati òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. 34A gba àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀ nígbà náà, a sì run wọ́n, ati ọkunrin, ati obinrin, ati àwọn ọmọ wọn. A kò dá ohunkohun sí, 35àfi àwọn ohun ọ̀sìn tí a kó bí ìkógun, pẹlu àwọn ìkógun tí a kó ninu àwọn ìlú tí a gbà. 36Láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni lọ, ati ìlú ńlá tí ó wà ní àfonífojì, títí dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó ju agbára wa lọ. OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn lé wa lọ́wọ́, 37àfi ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni nìkan ni ẹ kò súnmọ́, àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etí odò Jaboku, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní agbègbè olókè, ati gbogbo ibi tí OLUWA Ọlọrun wa ti paláṣẹ pé a kò gbọdọ̀ dé.

Currently Selected:

DIUTARONOMI 2: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy