YouVersion Logo
Search Icon

KOLOSE 1

1
Ìkíni
1Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti arakunrin wa, àwa ni à ń kọ ìwé yìí–
2Sí ìjọ eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Kolose, sí àwọn arakunrin tí ó jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi.
Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa kí ó wà pẹlu yín.
Adura Ọpẹ́
3À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa, Jesu Kristi, nígbà gbogbo tí a bá ń gbadura fun yín. 4A ti gbúròó igbagbọ yín ninu Kristi Jesu ati ìfẹ́ tí ẹ ní sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. 5Ìrètí tí ó wà fun yín ni ọ̀run, tí ẹ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìn rere, ni orísun igbagbọ ati ìfẹ́ yín. 6Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́. 7Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere lọ́dọ̀ Epafirasi, àyànfẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa.#Kol 4:12; File 23 8Òun ni ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín ninu nǹkan ti ẹ̀mí.
9Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí. 10A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun. 11-12Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀.
Ẹni Tí Kristi Jẹ́ ati Iṣẹ́ Rẹ̀
13Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀. 14Nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ yìí ni a fi ní ìdáǹdè, àní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa.#Efe 1:7
15Eniyan kò lè rí Ọlọrun, ṣugbọn ọmọ yìí ni àwòrán rẹ̀, òun ni àkọ́bí ohun gbogbo tí a dá.#Ọgb 7:26 16Nítorí pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, lọ́run ati láyé: ati ohun tí a rí, ati ohun tí a kò rí, ìbáà ṣe ìtẹ́ ọba, tabi ìjọba, tabi àwọn alágbára, tabi àwọn aláṣẹ. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá gbogbo nǹkan, nítorí tirẹ̀ ni a sì ṣe dá wọn. 17Ó ti wà ṣiwaju ohun gbogbo. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo nǹkan sì fi wà létò. 18Òun ni orí fún ara, tíí ṣe ìjọ. Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí tí a jí dìde láti inú òkú, kí ó lè wà ní ipò tí ó ga ju gbogbo nǹkan lọ.#Efe 1:22-23 19Nítorí ó wu Ọlọrun pé kí ohun tí Ọlọrun tìkararẹ̀ jẹ́ máa gbé inú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. 20Nípa rẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbogbo nǹkan lọ́kan pẹlu ara rẹ̀, kí alaafia lè dé nípa ikú rẹ̀ lórí agbelebu. Gbogbo nǹkan wá wà ní ìṣọ̀kan, ìbáà ṣe nǹkan ti ayé tabi àwọn nǹkan ti ọ̀run.#Efe 2:16
21Ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ àlejò ati ọ̀tá ninu ọkàn yín nípa iṣẹ́ burúkú yín 22ni Ọlọrun wá mú wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara rẹ̀ nípa ikú ọmọ rẹ̀, kí ó lè sọ yín di ẹni tí ó mọ́, tí kò ní àbùkù, tí kò sì ní ẹ̀sùn níwájú rẹ̀, 23tí ẹ bá dúró ninu igbagbọ, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ dúró gbọningbọnin, tí ẹ kò kúrò ninu ìrètí ìyìn rere tí ẹ ti gbọ́, tí èmi Paulu jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, tí a ti waasu rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ayé.
Iṣẹ́ Paulu sí Ìjọ Ọlọrun
24Ní àkókò yìí, mo láyọ̀ ninu ìyà tí mò ń jẹ nítorí yín. Ìyà tí mò ń jẹ ninu ara mi yìí ni èyí tí ó kù tí Kristi ìbá jẹ fún ìjọ, tíí ṣe ara rẹ̀. 25Nítorí èyí ni mo ṣe di iranṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ọlọrun ti fún mi láti ṣe nítorí yín. 26Ìjìnlẹ̀ àṣírí nìyí, ó ti wà ní ìpamọ́ láti ìgbà àtijọ́ ati láti ìrandíran, ṣugbọn Ọlọrun fihan àwọn eniyan rẹ̀ ní àkókò yìí. 27Àwọn ni ó wu Ọlọrun pé kí wọ́n mọ ọlá ati ògo àṣírí yìí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Àṣírí náà ni pé, Kristi tí ó ń gbé inú yín ni ìrètí ògo. 28Kristi yìí ni à ń kéde fun yín, tí à ń kìlọ̀ rẹ̀ fún gbogbo eniyan, tí a fi ń kọ́ gbogbo eniyan ní gbogbo ọgbọ́n, kí á lè sọ gbogbo eniyan di pípé ninu Kristi. 29Ohun tí mò ń ṣiṣẹ́ fún nìyí gẹ́gẹ́ bí agbára tí Ọlọrun fún mi, tí ó ń fún mi ní okun.

Currently Selected:

KOLOSE 1: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy