YouVersion Logo
Search Icon

ÀWỌN ỌBA KEJI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àwọn Ìtàn inú ìwé yìí jẹ́ àfikún ti inú Ìwé Àwọn Ọba Kinni, nípa ìjọba ìpínfẹ̀ àwọn ẹ̀yà Israẹli, ti àríwá ati ti gúsù. Ọ̀nà meji pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé yìí sí: (1) Ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ mejeeji láti nǹkan bíi ààrin sẹntiuri kẹsan-an (9th Century B.C.), kí á tó bí OLUWA wa títí di àkókò ìṣubú Samaria ati òpin ìjọba ìpínlẹ̀ àríwá ní ẹẹdẹgbẹrin ó lé mejilelogun ọdún (722 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. (2) Ìtàn ìjọba ìpínlẹ̀ Juda láti àkókò ìṣubú ìjọba ìpínlẹ̀ Israẹli títí di ìgbà tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó Jerusalẹmu nígbèkùn, tí ó sì pa á run ní ọrinlelẹẹdẹgbẹta ó lé mẹfa ọdún (586 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. Ní òpin ìtàn inú ìwé náà, a rí ìtàn Gedalaya gomina Juda lábẹ́ àṣẹ àwọn ará Babiloni ati àkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe dá Jehoiakimu ọba Juda sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n ní Babiloni.
Àwọn ìdàrúdàpọ̀ wọnyi dé bá àwọn ọba ati àwọn ọmọ Israẹli ati Juda nítorí aiṣododo wọn. Ohun ìyanu ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi jẹ́ ninu ìtàn àwọn ọmọ Israẹli.
Ipa pataki ni Wolii Eliṣa tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Wolii Elija kó ninu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Àwọn Ọba Keji.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Orílẹ̀-èdè Israẹli pín sí meji 1:1–17:41
a. Wolii Eliṣa 1:1–8:15
b. Àwọn Ọba Juda ati Àwọn Ọba Israẹli 8:16–17:4
d. Ìṣubú Samaria 17:5-41
Ìjọba ìpínlẹ̀ Juda 18:1–25:30
a. Láti orí Hesekaya dé Josaya 18:1–21:26
b. Ìjọba Josaya 22:1–23:30
d. Àwọn ọba tí wọ́n jẹ kẹ́yìn ní Juda 23:31–24:20
e. Ìṣubú Jerusalẹmu 25:1-30

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy