YouVersion Logo
Search Icon

SAMUẸLI KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Kókó ohun tí ó wà ninu Ìwé Kinni ti Samuẹli ni àkọsílẹ̀ àyípadà ètò ìjọba Israẹli, láti ìjọba Àwọn Onídàájọ́ sí ìjọba tí àwọn ọba gidi jẹ́ olórí ati aláṣẹ ìlú. Àwọn eniyan mẹta pataki ni àyípadà yìí kàn gbọ̀ngbọ̀n. Àyípadà ìjọba yìí ṣẹlẹ̀ ní àkókò Samuẹli, òun ni ó jẹ oyè onídàájọ́ kẹ́yìn ní Israẹli. Ẹnìkejì ni Saulu; òun ni ọba tí ó kọ́kọ́ jẹ ní ilẹ̀ Israẹli. Dafidi ni ẹni kẹta. Ó rí ọpọlọpọ ìrírí nípa àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ lákòókò Samuẹli ati Saulu, kí ìjọba rẹ̀ tó fi ìdí múlẹ̀.
Ní ṣókí, ohun tí ìwé yìí ń sọ, gẹ́gẹ́ bíi ti inú àwọn ìwé ìtàn Majẹmu Laelae yòókù ni pé, títẹ̀lé àṣẹ Ọlọrun a máa kó ire bá eniyan; ṣugbọn ìjìyà ni èrè ẹ̀ṣẹ̀ ati lílòdì sí àṣẹ Ọlọrun. Èyí hàn ketekete ninu iṣẹ́ tí OLUWA rán sí wolii Eli ní orí 2 ẹsẹ 30, pé, “N óo buyì fún ẹni tí ó bá buyì fún mi, n óo sì kọ ẹni tí ó bá kọ̀ mí sílẹ̀.”
Ìwé yìí ṣe àkọsílẹ̀ ire ati ibi tí ó wà ninu yíyan ọba fún àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA ni Ọba lórí wọn tẹ́lẹ̀, ṣugbọn nígbà tí wọn bèèrè fún ọba láàrin ara wọn, OLUWA yàn án fún wọn. Ohun tí ó ṣe pataki jù ni pé, ati ọba tí wọ́n yàn ati àwọn ọmọ Israẹli yòókù, Ọlọrun ni aláṣẹ ati onídàájọ́ lórí gbogbo wọn (2:7-10). Ní abẹ́ òfin Ọlọrun, gbogbo eniyan pátá, ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ọ̀kan náà ni wọ́n, olukuluku ni ó sì ní ẹ̀tọ́ tirẹ̀, láìsí ìrẹ́jẹ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Samuẹli gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ ní Israẹli 1:1–7:17
Saulu jọba 8:1–10:27
Àwọn ọdún tí Saulu kọ́kọ́ lò lórí oyè 11:1–15:35
Dafidi ati Saulu 16:1–30:31
Ikú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin 31:1-13

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy