YouVersion Logo
Search Icon

ÀWỌN ỌBA KINNI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Àwọn Ọba Kinni jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìtàn àwọn ọba Israẹli, tí ìtàn wọn bẹ̀rẹ̀ ninu àwọn Ìwé Samuẹli. Ọ̀nà mẹta pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé yìí sí: (1) Bí Solomoni ṣe jọba Israẹli ati ti Juda; ati ikú Dafidi, baba rẹ̀. (2) Àkókò ìjọba ati àṣeyọrí Solomoni–ní pataki àṣeyọrí kíkọ́ Tẹmpili ní Jerusalẹmu. (3) Pípín orílẹ̀-èdè náà sí meji, àwọn orílẹ̀-èdè ìhà àríwá ati ti ìhà gúsù; ati ìtàn àwọn ọba tí wọ́n jẹ lórí ìpín mejeeji láti ìgbà náà títí di ààrin sẹntiuri kẹsan-an, ká tó bí OLUWA wa (mid 9th Century B.C.)
Ninu ìwé Àwọn Ọba mejeeji ìhà tí ọba kọ̀ọ̀kan bá kọ sí Ọlọrun ni wọ́n fi ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Bákan náà, àṣeyọrí orílẹ̀-èdè wọn wà lọ́wọ́ irú ìhà tí wọ́n bá kọ sí Ọlọrun. Ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, ìjìyà ni ìwà àgbèrè ati àìgbọràn máa ń kó bá wọn. Gbogbo ọba tí ó jẹ ní ìhà àríwá ni wọn kò ṣe dáradára, ṣugbọn ní ti àwọn ọba Juda, àwọn mìíràn ninu wọn kò ṣe dáradára, àwọn mìíràn sì ṣe àṣeyọrí.
Ninu ìwé yìí àwọn wolii OLUWA ni wọ́n kó ipa pataki jùlọ, àwọn ni akikanju agbẹnusọ fún Ọlọrun, tí máa ń kìlọ̀ fún àwọn eniyan pé kí wọn má bọ̀rìṣà, kí wọ́n sì máa pa òfin Ọlọrun mọ. Wolii Elija jẹ́ akọni láàrin wọn; pàápàá nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ láàrin òun ati àwọn alufaa Baali (orí 18).
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Òpin ìjọba Dafidi 1:1–2:12
Solomoni jọba 2:13-46
Àkókò ìjọba Solomoni 3:1–11:43
a. Àwọn ọdún tí Solomoni kọ́kọ́ lò lórí oyè 3:1–4:34
b. Kíkọ́ Tẹmpili 5:1–8:66
d. Àwọn ọdún tí Solomoni lò kẹ́yìn lórí oyè 9:1–11:43
Pípín ìjọba orílẹ̀-èdè Israẹli sí meji 12:1–22:53
a. Àwọn ẹ̀yà àríwá yapa 12:1–14:20
b. Àwọn ọba Juda ati àwọn ti Israẹli 14:21–16:34
d. Wolii Elija 17:1–19:21
e. Ahabu Ọba Israẹli 20:1–22:40
ẹ. Jehoṣafati ọba Juda ati Ahasaya ọba Israẹli 22:41-53

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy