Àwọn èsì àwárí fún: hope
Hab 1:1 (YBCV)
Ọ̀rọ-ìmọ ti Habakuku wolii rí.
Hab 1:2 (YBCV)
Oluwa, emi o ti ke pẹ to, ti iwọ kì yio fi gbọ́! ti emi o kigbe si ọ, niti ìwa-ipa, ti iwọ kì yio si gbalà!
Hab 1:3 (YBCV)
Ẽṣe ti o mu mi ri aiṣedede, ti o si jẹ ki nma wò ìwa-ìka? nitori ikógun ati ìwa-ipá wà niwaju mi: awọn ti si nrú ijà ati ãwọ̀ soke mbẹ.
Hab 1:4 (YBCV)
Nitorina li ofin ṣe di ẹ̀rọ, ti idajọ kò si jade lọ li ẹtọ́; nitoriti ẹni buburu yí olododo ka; nitorina ni idajọ ẹbi ṣe njade.
Hab 1:5 (YBCV)
Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin.
Hab 1:6 (YBCV)
Nitoripe, wò o, emi gbe awọn ara Kaldea dide, orilẹ-ède ti o korò, ti o si yára, ti yio rìn ibú ilẹ na ja, lati ni ibùgbe wọnni, ti kì iṣe ti wọn.
Hab 1:7 (YBCV)
Nwọn ni ẹ̀ru, nwọn si fò ni laiyà: idajọ wọn, ati ọlanla wọn, yio ma ti inu wọn jade.
Hab 1:8 (YBCV)
Ẹṣin wọn pẹlu yara jù ẹkùn lọ, nwọn si muná jù ikõkò aṣãlẹ lọ: ẹlẹṣin wọn yio si tàn ara wọn ka, ẹlẹṣin wọn yio si ti ọ̀na jijìn rére wá; nwọn o si fò bi idì ti nyára lati jẹun.
Hab 1:9 (YBCV)
Gbogbo wọn o si wá fun ìwa-ipá; iwò oju wọn o si wà siwaju, nwọn o si kó igbèkun jọ bi yanrìn.
Hab 1:10 (YBCV)
Nwọn o si ma fi awọn ọba ṣẹsín, awọn ọmọ alade yio si di ẹni-ẹ̀gan fun wọn: gbogbo ibi agbara ni nwọn o si fi rẹrin; nitoripe nwọn o ko erupẹ̀ jọ, nwọn o si gbà a.
Hab 1:11 (YBCV)
Nigbana ni inu rẹ̀ yio yipadà, yio si rekọja, yio si ṣẹ̀, ni kikà agbara rẹ̀ yi si iṣẹ òriṣa rẹ̀.
Hab 1:12 (YBCV)
Lati aiyeraiye ki iwọ ti wà? Oluwa Ọlọrun mi, Ẹni Mimọ́ mi? awa kì yio kú. Oluwa, iwọ ti yàn wọn fun idajọ; Ọlọrun alagbara, iwọ ti fi ẹsẹ̀ wọn mulẹ fun ibawi.
Hab 1:13 (YBCV)
Oju rẹ mọ́ jù ẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò ìwa-ìka: nitori kini iwọ ha ṣe nwò awọn ti nhùwa arekerekè, ti o si pa ẹnu rẹ mọ, nigbati ẹni-buburu jẹ ẹniti iṣe olododo jù u run?
Hab 1:14 (YBCV)
Ti iwọ si nṣe enia bi ẹja okun, bi ohun ti nrakò, ti kò ni alakoso lori wọn?
Hab 1:15 (YBCV)
Iwọ ni àwọn lati fi gbé gbogbo wọn, nwọn nfi àwọn mu wọn, nwọn si nfi awò wọn kó wọn: nitorina ni nwọn ṣe nyọ̀, ti inu wọn si ndùn.
Hab 1:16 (YBCV)
Nitorina, nwọn nrubọ si àwọn wọn, nwọn si nsùn turari fun awò wọn; nitori nipa wọn ni ipin wọn ṣe li ọrá, ti onjẹ wọn si fi di pupọ̀.
Hab 1:17 (YBCV)
Nitorina, nwọn o ha ma dà àwọn wọn, nwọn kì yio ha dẹkun lati ma fọ́ orilẹ-ède gbogbo?
Hab 2:1 (YBCV)
LORI ibuṣọ́ mi li emi o duro, emi o si gbe ara mi kà ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yio sọ fun mi, ati èsi ti emi o fọ́, nigbati a ba mba mi wi.
Hab 2:2 (YBCV)
Oluwa si da mi lohùn, o si wipe, Kọ iran na, ki o si hàn a lara wàlã, ki ẹniti nkà a, le ma sare.
Hab 2:3 (YBCV)
Nitori iran na jẹ ti igbà kan ti a yàn, yio ma yára si igbẹhìn, kì yio si ṣeke, bi o tilẹ̀ pẹ, duro dè e, nitori ni dide, yio de, kì yio pẹ.
Hab 2:4 (YBCV)
Kiyesi i, ọkàn rẹ̀ ti o gbega, kò duro ṣinṣin ninu rẹ̀: ṣugbọn olododo yio wà nipa ìgbagbọ́ rẹ̀.
Hab 2:5 (YBCV)
Bẹ̃ni pẹlu, nitoriti ọti-waini li ẹtàn, agberaga enia li on, kì isi simi, ẹniti o sọ ifẹ rẹ̀ di gbigbõrò bi ipò-okú, o si dabi ikú, a kò si lè tẹ́ ẹ lọrun, ṣugbọn o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si ọdọ, o si gbá gbogbo enia jọ si ọdọ rẹ̀:
Hab 2:6 (YBCV)
Gbogbo awọn wọnyi kì yio ma pa owe si i, ti nwọn o si ma kọ orin owe si i, wipe, Egbe ni fun ẹniti nmu ohun ti kì iṣe tirẹ̀ pọ̀ si i! yio ti pẹ to? ati fun ẹniti ndi ẹrẹ̀ ilọnilọwọgbà ru ara rẹ̀.
Hab 2:7 (YBCV)
Awọn ti o yọ ọ lẹnu, kì yio ha dide lojiji? awọn ti o wahalà rẹ kì yio ha ji? iwọ kì yio ha si di ikogun fun wọn?
Hab 2:8 (YBCV)
Nitori iwọ ti kó orilẹ-ède pupọ̀, gbogbo iyokù awọn enia na ni yio kó ọ; nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa-ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.