Àwọn èsì àwárí fún: honor
Rom 12:10 (YBCV)
Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju.
Owe 21:21 (YBCV)
Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá.
Rom 12:1 (YBCV)
NITORINA mo fi iyọ́nu Ọlọrun bẹ̀ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na.
Rom 12:9 (YBCV)
Ki ifẹ ki o wà li aiṣẹtan. Ẹ mã takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ́ ohun ti iṣe rere.
Rom 12:12 (YBCV)
Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura;
Rom 12:15 (YBCV)
Awọn ti nyọ̀, ẹ mã ba wọn yọ̀, awọn ti nsọkun, ẹ mã ba wọn sọkun.
Rom 12:19 (YBCV)
Olufẹ, ẹ máṣe gbẹsan ara nyin, ṣugbọn ẹ fi àye silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi ó gbẹsan.
Rom 12:21 (YBCV)
Maṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi rere ṣẹgun buburu.
I. Kor 6:19 (YBCV)
Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmí Mimọ́, ti mbẹ ninu nyin, ti ẹnyin ti gbà lọwọ Ọlọrun? ẹnyin kì si iṣe ti ara nyin,
I. Kor 6:20 (YBCV)
Nitori a ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yìn Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmí nyin, ti iṣe ti Ọlọrun.
Filp 2:3 (YBCV)
Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.
Filp 4:8 (YBCV)
Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò.
Kol 3:23 (YBCV)
Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, kì si iṣe fun enia;
I. Pet 5:6 (YBCV)
Nitorina ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun, ki on ki o le gbé nyin ga li akokò.
O. Daf 46:10 (YBCV)
Ẹ duro jẹ, ki ẹ si mọ̀ pe emi li Ọlọrun, a o gbé mi ga ninu awọn keferi, a o gbé mi ga li aiye.
Owe 3:5 (YBCV)
Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ.
Owe 3:6 (YBCV)
Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ.
Owe 3:7 (YBCV)
Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi.
Mat 13:57 (YBCV)
Bẹ̃ni nwọn kọsẹ lara rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Kò si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu ati ni ile on tikararẹ̀.
Mat 15:4 (YBCV)
Nitori Ọlọrun ṣòfin, wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ati ẹniti o ba sọrọ baba ati iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀.
Mat 15:8 (YBCV)
Awọn enia yi nfi ẹnu wọn sunmọ mi, nwọn si nfi ète wọn bọla fun mi; ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.
Mak 6:4 (YBCV)
Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ko si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu on tikararẹ̀, ati larin awọn ibatan rẹ̀, ati ninu ile rẹ̀.
Luk 14:11 (YBCV)
Nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, li a o rẹ̀ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, li a o si gbéga.
Joh 5:23 (YBCV)
Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a.
Joh 12:26 (YBCV)
Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, ki o ma tọ̀ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibẹ̀ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun.