Àwọn èsì àwárí fún
Eks 27:10 (YBCV)
Ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ wọn, ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà.
II. Kro 34:11 (YBCV)
Awọn ọlọnà ati awọn kọlekọle ni nwọn fifun lati ra okuta gbigbẹ́, ati ìti-igi fun isopọ̀, ati lati tẹ́ ile wọnni ti awọn ọba Juda ti bajẹ.
Eks 27:11 (YBCV)
Ati bẹ̃ gẹgẹ niti ìha ariwa ni gigùn aṣọ-tita wọnni yio jẹ́ ọgọrun igbọnwọ ni ìna wọn, ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ rẹ̀ ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà.
Eks 26:4 (YBCV)
Iwọ o si ṣe ojóbo aṣọ-alaró si eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù, ati bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe li eti ikangun aṣọ-tita keji, ni ibi isolù keji.
Eks 36:11 (YBCV)
O si pa ojóbo aṣọ-alaró li eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù; bẹ̃ gẹgẹ li o ṣe si ìha eti ikangun aṣọ-tita keji nibi isolù keji.
Eks 26:3 (YBCV)
Aṣọ-tita marun ni ki a solù mọ́ ara wọn; ati aṣọ-tita marun keji ni ki a solù mọ́ ara wọn.
Eks 36:10 (YBCV)
O si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn: ati aṣọ-tita marun keji li o si solù mọ́ ara wọn.
II. Kro 34:12 (YBCV)
Awọn ọkunrin na fi otitọ ṣiṣẹ na: awọn alabojuto wọn ni Jahati ati Obadiah, awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Merari; ati Sekariah ati Meṣullamu, ninu awọn ọmọ Kohati, lati mu iṣẹ lọ; ati gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o ni ọgbọ́n ohun-elo orin.
Eks 26:5 (YBCV)
Ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ-tita kan, ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o si ṣe si eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji; ki ojóbo ki o le kọ́ ara wọn.
Eks 36:12 (YBCV)
Ãdọta ojóbo li o pa lara aṣọ-tita kan, ati ãdọta ojóbo li o si pa li eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji: ojóbo na so aṣọ-tita kini mọ́ keji.
II. Kro 34:10 (YBCV)
Nwọn si fi i le ọwọ awọn ti nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto iṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi i fun awọn aṣiṣẹ ti nṣiṣẹ ile Oluwa, lati tun ile na ṣe:
Eks 27:9 (YBCV)
Iwọ o si ṣe agbalá agọ́ na: ni ìha gusù lọwọ ọtún li aṣọ-tita agbalá ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti ọgọrun igbọnwọ ìna, yio wà ni ìha kan:
Eks 27:12 (YBCV)
Ati niti ibú agbalá na, ni ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ yio wà: opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa.