Ìmọ́lẹ̀ Ayé - Ìfọkànsìn AdventiÀpẹrẹ

Àlàáfíà
Omo Aládé Àlàáfíà
Láti ọwọ́ Pastor Maxim Belousov, Alájọṣepọ̀ pẹ̀lú OneHope ní Ukraine
“Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ́ nínú Kristi Jesu.” — Fílípì 4:7
Àlàáfíà kò wọ́ pọ̀ nínú ìgbé Palesitini ní ìgbà àtijó.
Kò nira láti ro ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ún sọ bí wọ́n ṣe ń ṣọ́ àwọn àgùntàn wọn níbi tí wọ́n ti ń yáná ní alẹ́ kínní Kérésìmesì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn. Títí di ìgbà wo ni a máa gbé nínú ẹ̀rù? Nígbà wo ni èyí yóò dópin? Kíni ó ṣe tí Ọlọ́run fi gbà ǹkan burúkú báyìí láàyè láti ṣẹlẹ̀ sí wa? Ǹjẹ́ àlàáfíà yóò jẹ́ ti àwọn ènìyàn wa rárá bí? Ìdílé wa? Awa pàápàá?
Ṣùgbọ́n nínú àwọn ìbéèrè tí kò rọrùn yìí, iyèméjì, àti àníyàn, Ọlọ́run ń kọjá nínú àkókò tí ó ṣe ókùnkùn ribiribi jù nínú ayé wọn láti ipasẹ̀ áńgẹ́lì láti fún wọn ní ìdánilójú.
Pẹ̀lú ògo Ọlọ́run tí ó ń tàn yíká, áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn — àti ìwọ náà — wípé ohun tí o n là kọjá kò ṣe ẹ̀yin Ọlọ́run. Ó mọ̀ ẹ̀rù rẹ ṣùgbọ́n o kò nílò láti bẹ̀rù nítorí pé Ó wà ní ìṣàkóso. Mèsáyà rẹ́ ti dé!
Ní báyìí àwọn ọ̀rọ̀ tí kìí ṣe àjòjì láti inú Lúùkù 2:14 —
"Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, àti lí ayé àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn."
Sí ọmọbìnrin kan ni Síríà tí ó ti pàdánù àwọn òbí àti àbúrò ọkùnrin rẹ̀ kékeré nípasẹ̀ àdó olóró, ọ̀rọ̀ yìí ń ṣe ìlérí wípé ogun yìí yóò dópin.
Fún ìyá tí a ti fa ọkàn rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí ìkúndùn oògùn olóró, wọ́n jẹ́ atọ́ka sí ìgbẹ̀yìn ẹ̀bi àti ìdí fún ìrètí.
Fún èmi àti ìwọ — ẹ̀bùn Kérésìmesì tí kò ṣeé dá iye lé ni. Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì fi ògo fún Ọlọ́run: a ti bí Olùgbàlà, Ọmọ aládé Àlàáfíà ti dé!
Kókó Àṣàrò
Nípasẹ̀ ìbí Jésù Krístì, Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìrírí àlàáfíà Rẹ̀ tí kò ní ìpẹ̀kun kí á sì tún lè rìn nínú ojú rere Rẹ̀. Ní agbọndan ayé rẹ wo ni o ti nílò ìlérí àlàáfíà? Kíni ìbéèrè àti ìlàkàkà tí Ọlọ́run n fún ọ ní ìdánilójú lé lórí?
Ẹ̀bẹ̀ Àdúrà
Gb'àdúrà fún àwọn ọmọ Síríà tí wọ́n ń sá àsálà àti gbogbo àwọn tí wọ́n ń da ojú kọ ìdágìrì ogun ní àkókò Kérésìmesì láti ní ìrírí àlàáfíà àti ìtùnú Ọlọ́run.
Gb'àdúrà fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ Kérésìmesì ti OneHope ní Ukraine àti jákèjádò ilẹ̀ aláwọ̀ funfun — pé kí àwọn ọkàn ṣí payá sí Ìhìnrere, àti pé kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ìdílé wọn, pé kí wọn ó gba ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.
Yíyọ Ayọ̀ Kérésìmesì ní ìlú Ukraine
Àwọn ará Ukraine máa n yọ ayọ̀ Kérésìmesì ní ọjọ́ 7, oṣù Kínní!
Ní àìsùn Kérésìmesì, àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ma ń pé jọ láti jẹun àti láti ṣe àríyá papọ̀. Àti ọmọdé àti àgbà ló máa ń lọ láti ojúlé dé ojúlé láti kọrin Kérésì, ti ẹ̀rín ti ọ̀yàyà, tí wọn yóò sì ma sọ ní'pa ìrètí Jésù Krístì.
"Shchedryk" jẹ́ ààyò orin Kérésìmesì tí a kọ lati ọwọ́ olùkọ orin ọmọ Ukraine Mykola Leontovych ní 1914. Ó ṣeé ṣe kí o mọ orin náà sí "Carol of the Bells."
Àwọn ọ̀dọ̀ fẹ́ràn láti máa lọ́wọ́ nínú orin kíkọ olọ́kanòjọ̀kan — àti pẹ̀lú àwọn akọrin àwùjọ — nínú àwọn ilé ìtajà àti òpópónà fún Kérésìmesì.
Àwọn ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ àti ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ma ń gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti na ọwọ́ àánú sí àwọn aládùúgbò wọn ní àkókò Kérésìmesì — bíbẹ ilé ìwòsàn wò àti ilé àwọn ọmọ aláìlóbìí láti fún wọn ní ẹ̀bùn àti láti sọ ìtàn Kérésìmesì. Àwọn ilé Ìjọ́sìn náà á máa ṣe ìsìn àbẹ́là, èyí tí ó ma ń kún fún àwọn onígbàgbọ́ àti àlejò.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni kárí ayé ni yíò ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì lọ́dún yìí. Adventi, ayẹyẹ àpẹẹrẹ tí ó ní ẹwà tí yíò yọrí sí Ọjọ́ Kérésìmesì, jẹ́ apákan ńlá ti àwọn ayẹyẹ Kérésìmesì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí o ṣe ń ka ìfọkànsìn Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Adventi yìí, ìwọ yóò ní ànfàní láti dara pọ̀ mọ́ra láti ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ láti àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré, ìwọ ó sì kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn ojú ìwòye àti àwọn àṣà alágbára wọn.
More