Elíshà: Ìtàn Ìgbàgbọ́ Tí ó pe ni NíjàÀpẹrẹ

Ní gbogbo ìgbésí-ayé Èlíṣà, a ríi pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe ló fara jọ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù. Ní Àwọn Ọba Kejì 4:8-37, Èlíṣà ṣe ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu tó jọ tí Jésù yí nígbàtí ó mú ọmọkùnrin obìnrin Súnémù náà lára dá. Nígbà tí Èlíṣà kọ́kọ́ bá obìnrin náà pàdé, inú-rere àti ìtọ́jú tó ṣe yàá lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó fi pinnu láti san-án lérè pẹ̀lú ohun tó lérò pé o nílò jùlọ lákòókò náà, èyí tí ńṣe ọmọ. Ọlọ́run fún obìnrin náà lọ́mọ, àmọ́ lẹ́yìn ọdún díẹ̀ ọmọkùnrin náà ṣ'aláìsí, obìnrin náà wá bèrè fún ìrànlọ́wọ́ Èlíṣà láti jí ọmọ náà padà sáyé. Àwon ǹkan méjì kan wà tó gba àkíyèsí nípa àyọkà yìí. Àkọ́kọ́ ni ọ̀nà tó yani lẹ́nu ti Èlíṣà gba láti jí ọmọ náà dìde nípasẹ̀ sísùn lóríi rẹ̀ ẹnu-sí-ẹnu, ojú-sí-ojú, àti ọwọ́-sí-ọwọ́. Èkejì ni àmì tó dájú pé ipá tí Èlíṣà kọ́kọ́ sà láti jì ọmọ náà dìde kò yọrí.
Ìgbà mélòó ni o ti bá ara rẹ ní ipò Èlíṣà? Ò ń bẹ Ọlọ́run láti se nǹkan kan láyé rẹ o sì mọ̀ dájú wípé Ó lè ṣeé, àmọ́ kò wá sí ìmúṣẹ ní ìgbà àkọ́kọ́ tí o bèrè. O lè gbà ọjọ́, oṣù, tàbí ọdún mélòó kan. Máṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí o kò bá ṣàṣeyọrí lákọ́kọ́. Máa gbàdúrà. Túbọ̀ máa ṣe àwárí Ọlọ́run. Ó ma mú ẹ̀bẹ̀ àdúrà rẹ wá sí ìmúṣẹ ní ọ̀nà àti àkókò tí ó sàn jù fún ọ. Má ṣe páyà kí o sì máa gbàdúrà. Kí ni ohun kan tí o ti ń bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run àmọ́ tí kò tíì sí ìdáhùn? Kí ni o lè se láti rí i pé o kò juwọ́ ṣílẹ̀ nínú bíbèrè àti ṣíṣe àwárí Ọlọ́run nínú àdúrà fún ǹkan yìí?

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Èlíshà jẹ́ ọkàn lára àwọn ènìyàn tí ó ya ni l'ẹ́nu jùlọ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó je wòlíì tí ìgbàgbọ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹẹ dàbí ohun tí ó nira láti gbàgbọ́. Nínú òǹkà ọlọ́jọ́ mẹ́tàlá yìí, ẹ ma ka ìgbé ayé Elíshà já, ẹ sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwòkọ́ṣe rẹ̀ nípa bí ayé ṣe lè rí nígbà tí ẹ bá jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún Olúwa, kí ẹ sì pinu láti gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ tí ó pe ni níjà.
More
We would like to thank Pastor Craig Groeschel and Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.Life.Church