Àwọn Irúgbìn: Kíni àti Ìdí Àpẹrẹ

Seeds: What and Why

Ọjọ́ 2 nínú 4

Day 2- ÌRÚGBÌN TÚNTÚN KAN

Nígbàtí a bá bí àwọn ọmọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ́ ni àwọn ọrẹ àti ìbátan gbádùn láti máà tọ́ka sí àwọn ìwà ìkókó náà tí ó ṣe àfijọ tí bàbá àti ìyá wọ́n. A ń ṣe èyí nítorí a mọ wípé ọmọ náà wá láti irúgbìn àwọn òbí wọn, wọ́n sì jẹ alábàápín irú àwọn èròjà àjogúnbá tí ó ní àfijọ ara wọn. Bí ọdún ṣe ń kọjá lọ, a ṣe àkíyèsí wípé àwọn ìjọra tí ó wà kọjá èyí tí a lè fi ojú rí lọ. Àwọn ọmọdé a máà ṣe àwòkọ́ṣe ìhùwàsí, ìlànà ìrònú, ọgbọ́n, ẹ̀bùn, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ, pẹ̀lú àwọn òbí wọn!

Ọ̀dọ̀ tani ó ti jáde wà? Àwọn èròjà wo ni o mu láti ọ̀dọ̀ wọn? Kíni àwọn ènìyàn ní lérò nígbà tí wọ́n bá gbọ́ orúkọ ìdílé rẹ? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí a máà mú kí àwọn ónkàwé kan dúpẹ ṣùgbọ́n a máà kò ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn míràn. Tí ó bá jẹ èròjà ti a gbá láti ọ̀dọ̀ àwọn asíwájú wa nìkan ni, ṣe àyànmọ́ wa ni nígbà yẹn, láti jẹ ki wọn jẹ òbí wa ni ọ̀nà kan tàbí òmíràn?

Ní ibi yi ni Jésù ti dà sí!

(1 Jòhánù 3:9, [AMP])

“Ko si ẹni ti a bi lati ọdọ Ọlọrun [tí a pilẹ̀ṣẹ̀ rẹ, tí a mọọmọ dá, àti èyí tí a dá nípa aṣa] ti ń dán ẹ̀ṣẹ̀ wo, nítorí irúgbìn Ọlọ́run [Ìlànà igbesi aye Rẹ, kókó iwa ododo Rẹ̀] wá síbẹ̀ [ni pipe] nínú rẹ [ẹnití a tún bí — tí a tún bí láti òkè— tí ẹ̀mí ti yípadà, sọ di ọtun, tí a yà sọtọ fún eté Rẹ̀]; àti Òun [ẹni tí a tún bí] kò sì lè máà gbé ìgbésí ayé tí ó ní àṣà pẹ̀lú] dẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé a bí nípasẹ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sapá láti tẹ́ Ẹ́ lọ́run” (1 Jòhánù 3:9, [AMP]).

Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó ti di àtúnbí, ó ti ní àpẹẹrẹ, èròjà àti DNA tí ẹ̀mí tí Baba rẹ nínú rẹ!, Eléyìí túmọ̀ sí wípé ìmúsagbára wa nísinsìnyí tí dì àìlópin, àti pé a jẹ ara kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run

(Gálátíà 3:26, [AMP])

“Fun ẹ̀yin [ti o dì àtúnbí ni a ti túnbí láti òkè wa— ti ẹ̀mí ti yípadà, sọ di ọtun, ti a sọ di mimọ ati] gbogbo wa jẹ ọmọ Ọlọrun [ti a ya sọtọ fun eté Rẹ̀ pẹlu àwọn ẹtọ ati àwọn ànfàní ni kíkún] nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù” (Gálátíà 3:26, [AMP])

Nígbàtí ẹnikan nínú ẹbí bá kọjá lọ, àyàfi ti àkọsílẹ̀ nípa ogún pínpín bá wa bí bẹ́ẹ̀kọ, nipa àì-bìkítà ọmọ ẹbi ti o súnmọ́ julọ ni yíò jogun gbogbo ohun ti wọn ni. A ti rí wípé nínú irúgbìn túntún yí, a fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹtọ ati ànfàní gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run! Ogún yí kì í ṣe ohun tí a ní láti bá ẹnikẹ́ni jìjàdù fún, a ti bí wá sínú rẹ ná, tiwa ni sì í ṣe lọ́jọ́kọ́jọ́

Ṣé àṣàrò lórí nnkan ti o túmọ̀ sí láti ni Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá rẹ lónìí, kíni ó túmọ̀ sí láti jẹ ara kan náà gẹ́gẹ́ bí Òun fúnra Rẹ̀!

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Seeds: What and Why

Àwọn irúgbìn wà níbi gbogbo. Ọ̀rọ̀ rẹ, owó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìwọ alára, je irúgbìn! Báwo làwọn irúgbìn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa? Ẹ jẹ́ kí á wo ohun tí Bíbélì ní láti sọ, kí a sì wá rí bí ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa láti sún mọ́ Ọlọ́run àti ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Abundant Life Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ kàn sí https://alcky.com