A Ní Ìfẹ̀ẹ́ Rẹ̀ RékọjáÀpẹrẹ

O kò ní láti gbé pẹ̀lú ọkàn tí ó wúwo. Ọlọ́run ní àwọn ohun ọ̀pọ̀ síi fún ọ. Ọlọ́run n pe oníkálukú wa láti mọ̀ Ọ́n ní òtítọ́ àti láti rí ara wa pẹ̀lú ojú Rẹ̀. Ó fẹ́ kí a gbé nínú òmìnira àti ọkàn ìfúyẹ́.
Díẹ̀ nínú wa tí n gbé ní autopilot – a kò ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run a kò ṣì ṣe ohunkóhun pẹ̀lú ayé wa. A rò wí pé ìgbésí ayé wa kò ní iye l'órí bíi ti àwọn míràn, bíi wí pé a yàtọ̀ púpọ̀ tàbí wí pé a kò yàtọ̀ tó. A rí ara wa gẹ́gẹ́ bíi ẹni àìrí tàbí ẹni tí kò ṣe pàtàkì. Má ṣe gba àwọn irọ́ Ọ̀tá gbọ́.
Fún ẹni tí ó rí ara rè gẹ́gẹ́ bíi ẹni ẹ̀yìn, bíi àṣìṣe, tàbí bíi ẹni ààyè kejì… o ju ohun tí a ti sọ fún ọ lọ. Ọlọ́run pè ọ́ ní Àyànfẹ́ (1 Tẹsalóníkà 1:4).
O kò wà ní ibí ní àìròtẹ́lẹ̀, nítorí a lé ẹnìkan kúrò, ẹnìkan fi iṣẹ́ sílẹ̀, ẹnìkan kú, tàbí nítorí ẹnìkan ṣe àṣìṣe. Ìwọ kò wà ní ibí nítorí pé Ọlọ́run n ṣe ẹ̀dá ènìyàn ní ọ̀pọ̀, o sì ṣẹlẹ̀ wí pé o wà nínú èrò ìran yìí. A yàn ọ́ fún àkókò yìí, ní ibi tí o wà, ní ipò tí o wà, nítorí Ẹlédàá gbogbo àgbáyé sọ wí pé ó ṣe pàtàkì fún ọ l'áti wà ní ibí.
Ní 1 Korinti 12, Paulu sọ fún wa wí pé gbogbo wa jẹ́ ẹ̀yà pàtàkì ara kan náà, ara Kristi. Ẹsẹ̀ 18 sọ wí pé “Ọlọ́run fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú.”
Èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti mọ̀ọ́mọ̀ fi ọ́ sí ibi tí o wà. Ìṣe rẹ nínú ẹbí rẹ ṣe pàtàkì. Ipá rẹ nínú ẹgbẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ ṣe pàtàkì. Ẹni tí o jẹ́ ṣe kókó. Ọlọ́run yàn ọ́ fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní àyíká rẹ. Ẹni tí ìwọ jẹ́ gan-an jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún àwa yòókù.
Àyànfẹ́. Èyí ni orúkọ rẹ.
Fún ẹni tí ó ní èrò wí pé òhun kò ní agbára láti fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú ìgbésí ayé rẹ ní ojoojúmọ́, tí ó rò wí pé ìtàn rẹ̀ kò dára tó, t6abi wí pé ìgbésí ayé rẹ̀ kò lè ní ipa rárá… o ju ohun tí a ti sọ fún ọ lọ. Jésù pè ọ́ ní Òjísẹ́ Rẹ̀ sí ayé (Ise Awon Aposteli 1:8).
Àwa ni Ètò Àkọ́kọ́ Ọlọ́run–Ètò Rẹ̀ tí ó dára jù lọ- láti mú ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé tí ó jẹ́ okunkun.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ wí pé: “Ẹ̀rí Kristi ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní àárín yín.” ( 1 Kọ́ríńtì 1:6)
Àwọn àmuyè, ìtàn, ìwà, àti àwọn ìrírí ìgbésí ayé rẹ ni ó pèsè rẹ ní ọ̀nà àkànṣe láti fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú àwọn ìbátan rẹ.
Òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Èyí ni orúkọ rẹ.
Bí àkókò ìfọkànsìn wa papọ̀ ṣe n parí, mo fẹ́ gbà ọ́ ní ìyànjú pé kío máa tiraka láti lo àkókò gidi pẹ̀lú Ọlọ́run. Tẹ̀ sí iwájú ní ìtiraka láti lo àkókò láti bá A sọ ọ̀rọ̀, jẹ́ olóòótọ́ pẹ̀lú Rẹ̀, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, kí o sì fi ohùn Rẹ̀ ṣẹ èyí tí ó lọ sí òkè jù lọ ní ìgbésí ayé rẹ.
Ní òní yìí, mo fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́ yìí:
Ọlọ́run ò kò fún ọ ní orúkọ titun nìkan. Ó n sọ fún ọ ẹni tí o jẹ́ láti ẹ̀yìn wá. A ti fẹ́ràn rẹ láti ẹ̀yìn wá. Àyànfẹ. Ẹni tí a fẹ́. Àti ẹni tí ó yẹ láti jà fún.
Òtítọ́ ibẹ̀ ni èyí: A fẹ́ràn rẹ láti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ wá.
Mo pín àwọn irinṣẹ́ tí ó wúlò síi nípa bí o ṣe lè tún so pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, bí o se lè mọ ẹni tí o jẹ́, àti bí o ṣe lè gbé ayé yìí ní gbogbo ọjọ́ nínú ìwe tuntun mi, You Are More Than You’ve Been Told. Ní àpapọ̀, a lè lọ sí iwájú síi ní ìrìn àjò wa sí ìwòsàn àti òmìnira.
Nípa Ìpèsè yìí

Hosanna Wong mọ bí ó ṣe máa ń rí kí ènìyàn jẹ́ ẹni àìkásí, aláìyẹ́, àti éni tí a kò ní ìfẹ́ sí. Nínú ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí, ó tú orúkọ mẹ́sàn-án tí Ọlọ́run ń pè ọ palẹ̀, ó sì fún ọ ní ìwúrí tí ó wúlò, tí ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tààrà láti tú àṣírí irọ́, láti rí ara rẹ ní ìwòye ti Ọlọ́run, àti láti gbé ayé pẹ̀lú ìdúró déédéé àti ète tuntun.
More