Kórè Ìdúpẹ́ Yí Ọdún Ká!Àpẹrẹ

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ọjọ́ 3 nínú 7

WÁ S'ÍWÁJÚ RÈ̩ PÈ̩LÚ ÌDÚPẸ́!

"Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA; ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa! Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́; ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i. Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA, ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ." Orin Dáfìdì 95:1-3

N'ígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, àwọn kan máa ń jí pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́, wọn kìí sì fẹ́ kí nnkan kan dá wọn dúró láti má dìde kúrò lórí ibùsún wọn. Àwọn mìíràn máa yí aṣọ borí n'ígbà tí ọ̀yẹ̀ àárọ̀ bá là, wọn á mí kanlẹ̀ pẹ̀lú èrò pé àwọn kò fẹ́ d'ojú kọ ọjọ́ náà.

Ohun kan tí mo n'írètí pé a ó rí gbá mú nínú ẹ̀kọ́ yìí ni pé gbogbo ìgbà tí a kò bá sùn, a ní ànfààní l'áti wà n'íwájú Ọlọ́run! Báwo ni mo ṣe mọ èyí? Nítorí pé ní Kááfárì, aṣọ ìbòjú ya lát'òkè dé'lẹ̀ n'ígbà tí ilẹ̀ mì, èyí tó fún wa ní ànfààní l'áti wá s'íwájú ìtẹ́ pẹ̀lú ìgboyà. Ikú Jésù l'órí àgbéléèbú sán ọ̀nà fún wa l'áti wá s'íwájú Rẹ̀! A kò nílò àlùfáà mọ́ l'áti wọlé; ìwọ àti èmi leè wọlé b'ó ṣe wù wá!

Ní gbàrà tí a bá jí ní gbogbo àárọ̀, gbàrà tí a bá rí ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tí o ń tàn wọlé l'áti ojú fèrèsé wa, gbàrà tí a bá rí ojú sánmà tàbí tí a gbọ́ tí ẹyẹ ń k'ọrin, a ti wà n'íwájú Rẹ̀ l'ọ́nà kan, nítorí pé Òun ló dá ohun gbogbo. Báwo ni kí á ṣe kí Ọlọ́run? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kí á k'orin, k'á p'ariwo ayọ̀, kí á sì wá s'íwájú Rẹ̀ pẹ̀lú kínni? Pẹ̀lú ọpẹ́!

IṢẸ́ ÀKÀNṢE T'ÒNÍ:

• T'ó bá jẹ́ pé ìṣẹ̀dá tìrẹ ni l'áti máa kùn láàrọ́, dẹ́kun rẹ̀!

• Máa r'ẹ́rìn músẹ́ sí'ra rẹ ṣ'íwájú ìgbà tí o bá máa mu kọfí tàbí tíi.

• Kí àwọn ololùfẹ́ rẹ pẹ̀lú ìdùnnú kí o sì gb'ìyànjú l'áti wá ohun kan l'áti dúpẹ́ l'ọ́wọ́ wọn fún.

• Máa p'ariwo ayọ̀ bí o ṣe ń wa ọkọ̀ lọ s'íbi iṣẹ́ tàbí lọ ra nnkan l'ọ́jà.

Nípa Ìpèsè yìí

Harvest Thanksgiving All Year Round!

Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi àwọn ẹ̀kọ́ tí a le kọ́ láti àwọn àṣà míràn! Àwọn míràn lẹ̀ má ní ohun tí ayé ní ọ̀pọ̀, síbẹ̀ wọ́n fi àyè sílẹ̀ fún ayọ̀ àti ọkàn ọpẹ́ tí ó jinlẹ̀! Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ọkàn ọpẹ́ àti ayo jẹ́ àbùdá fún mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ bíi èémí mí! Nínú ètò yìí, a óò ṣe àwárí bí a tií fi sáà ọpẹ́ ṣe ìṣe ojojúmọ́!

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ ìránṣẹ́ Eternity Matters With Norma tí wọ́n ṣ'ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.facebook.com/eternitymatterswithnorma