Ìgboyà: Àgbéyẹ̀wò Ìgboyà Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn AláìpéÀpẹrẹ

Day 7: Pọ́ọ̀lù
Ní ọjọ́ kẹta, a ṣọ̀rọ̀ nípá ìgboyà Stéfánù, tí ó ń wàásù ìhìnrere Jésù bíótilẹ̀ jẹ́ wípé ó ná a ní ẹ̀mí rẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, ọkùnrin kan wà ní'tòsí tí ó kó ẹ̀wù àwọn tí ó pa Stéfánù lọ́wọ́. Orúkọ rẹ̀ ní Sọ́ọ̀lù. Ọ̀pọ̀ nínú wa ni ó mọ̀ ọ́ nítorí pé a yí i padà tinútẹ̀yìn nípasẹ̀ ìbápàdé tí ó ní pẹ̀lú Jésú tí ó yí orúkọ rẹ̀ àti ìṣe-pàtàkì ìgbésí-ayé rẹ̀ padà tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàású nípa Jésù dípò kí ó takò ó. Kódà, ọ̀pọ̀ ìwé Májẹ̀mú Tuntun ní Pọ́ọ̀lù kọ (ẹní tí à ń pè ní Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ni àwọn ìwé tí ó kọ sí àwọn ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ láti rí i dájú pé wọ́n gba òtítọ́ ìhìnrere Jésù dunjú.
Pọ́ọ̀lù jẹ́ onígboyà ènìyàn kàn làti ilẹ̀ wá, ṣùgbọ́n kiní kan ni o—ní àwọn apá ibìkan ó ṣe àṣejù. Bí ó tí kọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tí ó ṣe é gbámú nípa bí a ti í fẹ́ràn ara ẹni d'énú (wo Róòmù 12 àti 1 Kọ́ríntì 13), ẹlẹ́ran-ara ni òun náà. Lóòtọ́, ó ní láti bá àwọn ènìyàn wí l'ọ́pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n ní àwọn agbọn ibìkan, ó jọ bí ẹni pé ó rorò jù? Pọ́ọ̀lù kọ nínú Gàlátíà nípa ìtàpórógan rẹ̀ pẹ̀lú Pétérú (ẹni tí a kà nípa rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní. Ǹjẹ́ o rántí bí Pétérù ṣe ń sọ àsọjù? Wáá fi ojú inú wo Pọ́ọ̀lù àti Pétérù nínú àjọsọ-ọ̀rọ̀!). A kàá nínú Ìṣe ní apá ibìkan wípé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wọ̀'yá ìjà nípa pé bóyá kí ọkùnrin kan—Jòhánù Máàkú—darapọ̀ mọ́ wọn nínú ìrìn-àjò wọn (ìbátan Bánábà ni ọkùnrin yìí ṣùgbọ́n ó ti já wọn kulẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí nínú ìrìn-àjò wọn kan) wọ́n pínyà látàrí èyí! Pọ́ọ̀lù ní alábàárìn tuntun mìíràn (Sílà) Bánábà sì mú Jòhánù Máàkù gba ọ̀nà mìíràn lọ.
Gbogbo wa ni a lè ní "ìgboyà jú" dé ibi pé a gbàgbé láti ronú nípa tàbí ṣe ìkẹ́ àwọn ẹlòmíran ní àyíká wa, ṣúgbọ́n irú ìgboyà tí à ń sọ kọ́ ni èyí. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe kọ ọ́ pé, Ọlọ́run kò ì tíì j'áwọ́ l'ọ̀rọ́ wa; iṣẹ́ ṣì wà tí yíó ṣe. Ọlọ́run yió lo ohun tí a ṣetán láti fi fún Un; Ó ń rọra bá wa wí, Ó sì ń tọ wa ní ìgbà tí a bá fi ara wa sí'lẹ̀ fún Un. Bákan náà ní èyí jẹ́ fún àwọn tí ó wà ní sàkàání wa. Ní ìgbà tí èrò rẹ kò bá ṣe ọ̀kan pẹ̀lú ti ẹlòmíràn, tí ǹǹkan kò sì ṣ'ẹnuu re, èyí lè má jẹ́ òpin ọ̀rọ̀ náà—kò sí ẹni náà tí ó k'ọjá ìràpadà—Pọ́ọ̀lù sí mọ èyí dunjú. Síbẹ̀ ó fẹ́rẹ̀ sọ ìrètí nú lórí Jòhánù Máàkù—pátápátá. Nínú ìwé rẹ̀ sí ìjọ ní Kólósè, Pọ́ọ̀lù rán wọn létí àwọn ìtọ́ni tí ó fún wọn wípé ẹ má gba ẹnikẹ́ni m'ọ́ra àyàfi Jòhánù Máàkù, ẹni tí ó tí ní ìtàpórógan pẹ̀lú rí!
Bí o ṣe ń parí ọjọ́ méje yìí, mo gbàá l'ádùúrà pé kí o ní òye ìgboyà ní àrà ọ̀tọ̀. Ìgboyà kò ní láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tàbí tí a ní láti kéde fún gbogbo aráyé rí; kì í ṣe ohun tí ó la ariwo lọ tàbí tí ó ń mú inú bíni gẹ́gẹ́ bí o ṣe rò; ó dájú pé kì í ṣe àìní ìbẹ̀rù ní òdíwọ̀n rẹ̀, bíkòṣe àwọn ìgbésẹ̀ akin láì ka ìbẹ̀rù náà sí; àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìgboyà jẹ́ ìgbésẹ̀ fífi ohun gbogbo tí o ní fún Jésù àti gbígbé àbájáde rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
Àṣàrò/Ìbéèrè Ìjíròrò:
1. Ǹjẹ́ o ti jẹ́ "onígboyà àbaádí" rí tí ó sì ba àjọṣepọ̀ rẹ jẹ́ rí? Kíni ìgbésẹ̀ ìgboyà kan láti ọ̀dọ̀ rẹ tí ó lè mú kí àjọṣepọ̀ náà tún padà gún régé?
2. Èwo nínú àwọn ènìyàn inú ẹ̀kọ́ yìí ni ó jẹ mọ́ ọ jùlọ? Kíni ìdí?
3. Ìgbésẹ̀ wo ni o lè gbé ní ọ̀sẹ̀ tí ó ń bọ̀ yìí láti rìn nínú ìgboyà?
Nípa Ìpèsè yìí

Ìgboyà kò nílò láti jẹ́ ohun tí ó bùyààrì tí a sì ní láti pariwo rẹ̀ fún ayé rí; ó kàn jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú ohunkóhun tí o ní wá fún Jésù àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ lórí àbájáde wọn. Wá jẹ́ ká jọ rìn ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ méje láti wo bí àwọn ènìyàn aláìpé ṣe ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.
More