Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 5 nínú 10

Ninu ẹsẹ ìwé yii, Paulu sọ fun wa nipa iru imọ méjì tí ó wà. Ọkàn nínú wọn ni irú ìmọ̀ tí Ọlọ́run ti mọ pẹlu wa; èkejì ni bí a ṣe lè lo ìmọ̀ láti bá ara wa jẹ́ jẹ́ kí ó sì gbé ìgbéraga wọ̀ wa. Eléyìí wáyé nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sì ìjọ Kọ́ríńtì nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ lórí oúnjẹ tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà.

Nínú ẹsẹ iwé yí, Pọ́ọ̀lù sọ fún wa nípa oríṣi ìmọ̀ méjì tí ó wà. Ọ̀kan nínú wọn ni ìmọ̀ eléyìí tí Ọlọ́run mọ pẹ̀lú wa; ọ̀kan tó kù ní bí a ṣe lè lò ìmọ̀ láti bá ara wa Pọ́ọ̀lù kò sọ wípé ó dára tàbí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ṣùgbọ́n bóyá ṣíṣe àkóso lórí pípa àṣẹ bí ó ṣe yẹ́ ká jẹ. Àwọn kan nínú ìjọ ní ìmọ̀ tó ( pé) láti lè jẹ́ oúnjẹ tí a fi rúbọ si òrìṣà níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ wípé òrìṣà kò ní agbára kánkán lórí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìmọ̀ pípé yẹn náà, mú wá yapa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì rú àwọn ènìyàn sókè pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbéraga.

Ẹ jẹ́kí a jọ wo Kọ́ríńtì kíni 8:1-3 láti gbọ ọ̀nà tí ó dára jù láti ẹnu Pọ́ọ̀lù

  1. Ó wá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a fi rúbọ fún oriṣa. A mọ̀ pé, “Gbogbo wa ni a ní ìmọ̀,” "Ìmọ̀" eléyìí a máa mú kí eniyan gbéraga, ṣugbọn ìfẹ́ ní ń mú kí eniyan dàgbà.
  2. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun mọ nǹkankan, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò tíì ní mọ̀ tó bí ó ti yẹ.
  3. ‭Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn Ọlọrun, òun ni Ọlọrun mọ̀ ní ẹni tirẹ̀.

Pọ́ọ̀lù ń sọ wípé irú ìmọ̀ tí ó mú ìgbéraga àti ìpalára ènìyàn dání kí ì ṣe ìmọ̀ tòótọ́ rara(kò ì tí mọ ohun tí ó yẹ kí o mọ). Ṣùgbọ́n oríṣi ìmọ̀ kejì wá ti o yàtọ̀ sí ti àkọ́kọ́. Ìdáhùn Pọ́ọ̀lù sì ayédèrú ìmọ̀ yí ni ìfẹ́. Ìmọ̀ Ọlọ́run ti a lò lọ́nà tó bójú mú já sí ìfẹ́ fún Ọlọ́run, ati pé eléyìí ṣeé ṣe nítorí pé ó túmọ̀ sí bí a ṣe súnmọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ sì. Ọlọ́run fẹ́ kí àjọsepọ́ wá pẹ̀lú Òun dá bí ọrẹ kòríkòsùn tí kò sì pé àjọpín àṣírí wa.

‭Orin Dáfídì 25:14 (ESV) "Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́, a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn WỌ́N"

.

Ọ̀rọ̀ yi ni èdè Hébérù tí à ló fún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ni "Sod" tí ó sọ nípa irú ìmọ̀ràn àtàtà tí ó wà láti ọ̀dọ̀ ọrẹ tímọ́tímọ́ kan sì ìkejì. Bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ wá sí nìyẹn. Ó ń bá wa sọ̀rọ̀ láti inú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú tí ó ní àfọkàn-tán àti ìgbẹ́kẹ̀lé.Nítoríná dípò wíwà ìmọ̀ láti jẹ́ gàba lórí àwọn ènìyàn, Ọlọ́run fẹ́ kí a wá ìmọ̀ Òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́. Nígbàtí ó bá ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ó jinlẹ̀ pẹ̀lú ẹnìkan, ìwọ yíò rántí ohun tí wọn sọ, ohun tí wọn fẹ́ràn, ohun tí ó ń mú inú wọn dùn, àti ohun tí ó ń bá wọn lọ́kàn jẹ́. Bí Ó ṣe mọ̀ wá sí nìyẹn nísinsìnyí, àti pé Ó fẹ́ kí a túbọ̀ mò Òun síwájú sí kí a sì súnmọ́ Òun pẹ́típẹ́tí àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lójoojúmọ́ nítorípé Òun kò kan fẹ jẹ́ Olùgbàlà, Bàbá, àti olùrànlọ́wọ́ nìkan. Òun pẹ̀lú tun fẹ́ bá wà dọ́rẹ́.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church