KÉRÉSÌMESÌ: Ìmúṣẹ Ètò Ìdáǹdè Ọlọ́runÀpẹrẹ

Kíni ìṣe-pàtàkì wúńdía tí Màríà jẹ́? Kíni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì?
Òǹkọ̀wé ìhìnrere, Lúùkù, mọ̀ pé nípa títẹnumọ́ pé Màríà jẹ́ wúńdíá, òun yóò dáhùn àwọn ìhalẹ̀mọ́ni mẹ́ta àkọ́kọ́ sí ẹ̀sìn Krìstìẹ́nì:
- Yóò dáhùn àtakò àwọn Júù sí ẹ̀sìn Krìstìẹ́nì pé Jésù kì í ṣe àkàndá (àwọn Krìstìẹ́nì ń sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ inú Àìsáyà 7:14: ‘Wúńdía kan yóò l'óyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ni Ìmmánúẹ̀lì,’ jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù.).
- Yóò dáhùn sí ìgbàgbọ́ àwọn Docetic tí ó ń kọ́'ni pé Jésù kì í ṣe ènìyàn ẹlẹ́ran ara nítòótọ́. (Ó jẹ́ kó hàn kedere pé obìnrin ló bí Jésù).
- Yóò dáhùn sí èrò àwọn Onísọdọmọ tí ó wípé Jésù kì í ṣe ẹnìkan bàbàrà títí di ìgbà tí Ọlọ́run fi "sọ ọ́ di ọmọ rẹ̀" ní ìgbà tí ó dàgbà tán.
L'ẹ́nu kan, ìbí wúńdíá náà kọ́ni pé Jésù jẹ́ àkàndà, Ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn àti pé Ó jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ti yàn tẹ́lẹ̀ fún ìran ènìyàn.
Àti wípé láìsí ojúgbà: nípa ṣíṣe ètò fún wúńdíá kan láti bí Mèsáyà, Ọlọ́run ṣe ètò kí ohun tí kò ṣeé ṣe lè ṣeé ṣe nípasẹ̀ iṣẹ́ Ẹ̀mí rẹ̀.
Ó sì ń ṣe bákannáà lónìí.
Àdúrà
Baba Ọ̀wọ́n,
Kò ṣeé ṣe fún mi láti fi ojú inú wo bí mo ṣe lè jẹ́ ọmọ Rẹ, Ẹni tí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún.
Mo bu ọlá fún Ọ fún àǹfààní yìí, mo sì bèèrè pé kí n lè mú ète rẹ fún ìgbésí ayé mi ṣẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn òrìṣà èké tí àwọn ènìyàn mọ láti fi ṣe àpèjúwe òrìṣà kan tí wọ́n mọ̀ pé ó ní láti wà, kò ya'ni l'ẹ́nu pé, wọ́n jọ àwa ènìyàn gan-an. Wọ́n ní láti fi ìfọkànsìn mú wọn, kí wọ́n sì fún wọn ní rìbá kí wọ́n lè ṣe àkíyèsí wa. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń wá wa kiri––láti gbà wá padà sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Èyí gan-an ni ìtàn Kérésìmesì.
More