Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Sísọ Ọ̀rọ̀ ÌyèÀpẹrẹ

Speaking Life

Ọjọ́ 1 nínú 6

Agbára Orí Ahọ́n 



Ikú àti ìyè ló ń bẹ nínú agbára ahọ́n! Ǹjẹ́ ìwọ tilẹ̀ gba èyí gbọ́? Bí ahọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà kéréje, ó lè fọ àwọn èdè tó ní kìmí. Ẹ̀ṣẹ́ iná bíńtín, tó jẹ́ ǹkan kékeré bákannáà, lè jó aginjù ńlá. Ìtukọ̀ ọkọ̀ ojú-omi jẹ́ ǹkan kékeré míràn tó lè dárí ọkọ̀ ńlá. Nínú gbogbo ẹ̀yà ara, ahọ́n ló lágbára jù àti wípé ó lè jó gbogbo àgbáyé n'íná ó sì lè mí èémí ìyè sínú ọkàn tó pòrúru. Yan èyí tí o fẹ́.



Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi yé wa wípé àwọn ọ̀rọ̀ wa a máa dàbí iná ajónirun, tó lè ya ọ̀rẹ́, tó lè mú ìbínú wá, tó sì lè fa ìwà aṣiwèrè. Ní ìdàkejì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kí a mọ̀ wípé ahọ́n wa lè sọ̀rọ̀ tó ń mú ìyè wá…ọ̀rọ̀ bí àwòrán èso tí a fi wúrà gbẹ́, omi ìyè tàbí oyin fún ọkàn. Ọ̀rọ̀ wa a máa ní ipa rere tàbí búburú.



Ẹ̀bùn àrà-ọ̀tọ̀ tó ní ipa ni ahọ́n wa àti agbára ọ̀rọ̀ jẹ́. Nígbà tí a bá ka ìwé Òwe, a máa ṣe àkíyèsí wípé àwọn ẹsẹ̀ nípa agbára ọ̀rọ̀ ń jẹyọ léraléra. Òwe 12:6 kò wa wípé àwọn ọ̀rọ̀ wa lágbára láti wó ǹkan palẹ̀ àti agbára láti gbé dìde. Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ tí ń ti ahọ́n wa jáde ńṣe ìmúdúró àwọn ènìyàn àbí ṣeni ó ń fáwọn lulẹ̀? Tani ẹniti ń ṣàkóso ahọ́n rẹ? Tani kí a dá lẹ́bi nígbà tí àwọn ọ̀rọ̀ tí ń pani lára bá tẹnu wa jáde? Ó ṣe pàtàkì láti pinu wípé a ó máa ṣọ́ ǹkan tí ń ṣẹ̀wá látorí ahọ́n wa.



Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ rere, àti èyí tí ń runi sókè lè ṣiṣẹ́ ìwòsàn pẹ̀lú ìwúrí, a ní láti máa sọ irú ọ̀rọ̀ yí lóòrè-kóòrè. Nígbà tí a bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú inú kan, èyí lè yí ayé ẹni tí a sọ ọ̀rọ̀ náà sí padà. Fara balẹ̀ láti ṣe àyèwò bí o ti ń báni sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tìrẹ ma ń mú ìwúrí bá àwọn ènìyàn láti gbé ohun ńlá ṣe? Ṣé ọ̀rọ̀ tìrẹ ń ṣiṣẹ́ ìgbárùkù àti ìrànwọ́ fún ẹni tí ń jẹ̀yà? Ṣé ọ̀rọ̀ rẹ ńṣe ìtọ́jú, ìtura, àti ìwúrí fún àwọn ọmọ tí o bí?



Ó bani nínú jẹ́, wípé àwọn ẹ̀dùn bíi ìkórìíra, ìbẹ̀rù, ìbínú, iyèméjì, àti ìpinilẹ́mìí lè ti inú ọ̀rọ̀ jẹyọ. Bóyá ọ̀rọ̀-kíkọ ni tàbí èyí tí a sọ, wọ́n lágbára láti ba àlàáfíà àyíká àti ìbáṣepọ̀ jẹ́.



L'ọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, mo pinu láti pe ara mi níjà bí ó ti wà nínú Éfésù 4:29 tí ó wípé, “Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kankan kò gbọdọ̀ ti ẹnu yín jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rere, tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nígbàkúùgbà ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfaani.” Ẹ wo ìtọ́ni tó lágbára yìí. Iṣẹ́ ńlá láti kó ahọ́n ní ìjánu ni èyí jásí. Láìsí àwọn ọ̀rọ̀ tí ń pani lára, ara mí yá láti tẹ̀síwájú lórí ìrìn-àjò ìmúbọ̀sípọ̀ náà. Ó jẹ́ ìlépa mi láti sọ̀rọ̀ ìyè sínú ayé mi pẹ̀lú ahọ́n ara mi.



Lẹ́yìn tí a ti fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ wípé ahọ́n lágbára ìyè àti ikú, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àgbéyèwò ọ̀rọ̀ tí à ń sọ àti ọ̀nà tí à ń gbà gbe kalẹ̀. Gbé ọ̀rọ̀ rẹ sórí òṣùwọ̀n. Ọ̀rọ̀ rẹ lè yí ohun gbogbo padà! 



Gba èyí rò:



Bíńtín ni. Ó yára. Ó sì rọrùn. Àmọ́ yẹ ipa ọ̀rọ̀ rẹ wò. Ọ̀nà wo lo lè gbà láti túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ ìyè dípò ọ̀rọ̀ tí ń ba ǹkan jẹ́?



Gbàdúrà:



Olúwa jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àkíyèsí tó péye sí agbára orí ahọ́n àti àwọn ọ̀rọ̀ tí mo yàn láti sọ. Ràn mí lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ ìyè dípò ti ikú.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Speaking Life

Ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó kún fọ́fọ́ fún agbára! Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń múni ró tàbí èyí tí ń fani lulẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń fúnni ní ìyè tàbí èyí tí ń mú ikú wá. Èyí tí o yàn wá kù sí ọ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká jọ ṣe àgbéyẹ̀wò a...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Roxane Parks fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.roxanneparks.com/home.html

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa