Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣáájú ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Aáwọ̀
Ìrètí aáwọ̀
Kò sí bí aáwọ̀ kò ti ní wáyé nínú ìbáṣepọ̀.
Ìpèníjà ibẹ̀ kìí ṣe wípé bóyá ẹnu wa kòní kò nípa ǹkan; ǹkan tó jà jù ni ọ̀nà tí à ń gbà yanjú àwọn aáwọ̀ wa. Ǹkan tó ṣe pàtàkì jù fún gbogbo lọ́kọ-láyà ni láti ní àwọn ohun èlò àti àmúyẹ tí a fi lè pẹ̀tù sí aáwọ̀ ní ìrọ́wọ́-rọsẹ̀.
Kíkojú ìbínú
Ìbínú tìkára rẹ̀ kìí ṣe àìda; ọ̀nà tí à ń gbà bínú ló lè kó ìjàmbá bá ìbáṣepọ̀ wa.
Ẹranko méjì ma ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàlàyé àwọn ọ̀nà méjì tó burú tí kò sì tọ̀nà láti kojú ìbínú wa:
- Àgbáǹréré (Rhinos): èyí ma jẹ́ kí o mọ̀ lójú ẹsẹ̀ wípé òhun ń bínú -- wọn a sì máa ṣe ìkọlù
- Eku ẹlẹ́gùn-ún (Hedgehogs): àwọn wọ̀nyí máa ń fi ìbínú wọn pamọ́ -- nígbà ìbínú wọ́n sábà ma ń dákẹ́ tàbí fà sẹ́yìn
Àwọn ènìyàn tó dàbí àgbáǹréré àti eku ẹlẹ́gùn-ún ló ní láti kọ́ bí a ti ń sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn láì mú ariwo dání.
Wíwá ojútùú lápapọ̀
Nígbà tí aáwọ̀ bá dé:
- ṣe àkíyèsí wípé nínú ìgbéyàwó apá kan náà ni ẹ̀yin méjèèjì ń jà fún
- lápapọ̀ ẹ ṣe àwárí ojútùú tí yóò dára fún ìbáṣepọ̀ yín
- wà ní ìmúrasílẹ̀ láti tẹ 'ìjánu' nígbà tí ó yẹ àti wípé 'ṣe ibi tí ẹ wà lákòókò náà jẹ́ ibi tí ó dára láti máa sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ?'
Ìgbésẹ̀ márùn-ún láti wá ojútùú
- Ẹ dá ohun tó ń fa aáwọ̀ mọ̀ kí ẹ sì dójú sọọ́.
Ẹ fa ohun tí ń fa aáwọ̀ jáde láàrín yín. Ẹ gbée ka iwájú kí ẹ sì yanjú rẹ̀ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀. - Lo gbólóhùn tó ní ‘èmi’ nínú
Tiraka láti má sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn (fún àpẹrẹ: ‘Ìwọ ló máa ń…’ / ‘Ìwọ kìí…’). Ṣàlàyé ohun tí ń gbé ọ lọ́kàn (fún àpẹrẹ: ‘Inú mi kò dùn sí…’). - Tẹ́tí sí ẹnìkejì
Tiraka láti ní òye nípa àwọn ǹkan tó jẹ ẹnìkejì lógún. Ẹ ṣe sùúrù fúnra yín níbi ìtàkùrọ̀sọ. - Ẹ jọ ṣe àṣàrò nípa àwọn ojútùú tó ní ìtumọ̀
Ẹ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò ní onírúurú ọ̀nà. Ìbá dára tí ẹ bá lè ṣe àkọsílẹ̀ gan. - Ẹ yan ojútùú tó dára jù lákòókò yí kí ẹ sì máa ṣe àtúnṣe bí ẹ ti ń tẹ̀síwájú
Tí ojútùú tí ẹ yàn kò bá ṣiṣẹ́, ẹ gbìyànjú láti lo òmíràn látinú àkọsílẹ̀ ìṣáájú. Tí ẹ kò bá rí ojútùú síbẹ̀, ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.
Ìgbésẹ̀ láti ní ìmúláradá kúrò nínú ìpalára
Ìpalára kò ṣeé sá fún nínú ìgbéyàwó, a sì gbọ́dọ̀ ní ìmúláradá kúrò nínú ìpalára yìí tí ìbáṣepọ̀ wa bá máa gbèrú síi.
Ìgbésẹ̀ ìmúláradá kan wà tó rọrùn ṣùgbọ́n tó lágbára:
- Jíròrò nípa ìpalára náà
Jẹ́kí ẹnìkejì rẹ mọ̀ tí ó bá ṣẹ̀ ọ́. Máṣe fi ìpalára pamọ́ sínú ọkàn rẹ tàbí gba ìkẹ́dùn àti ìkórìíra láàyè láti gbilẹ̀ nínú rẹ. - Tọrọ ìdáríjì
Ìgbéraga lè mú kí ìtọrọ fún ìdáríjì nira fún wa. Nígbà tí a bá bẹ̀bẹ̀ fún àṣìṣe wa, èyí túmọ̀ sí gbígbà wípé a jẹ̀bi. Títọrọ ìdáríjì yí yóò wá ṣílẹ̀kùn fún ìmúbọ̀sípò ìbárẹ́. - Dáríjì
Ìdáríjì ni ipa tó yára jù sí ìmúláradá nínú ìgbéyàwó.
Ìdáríjì KÌÍ ṢE:
- gbígbàgbé ìpalára tó ṣẹlẹ̀
- dídíbọ́n wípé kò jámọ́ ǹkankan
- àìlè gbéná wojú ẹnìkejì wa nípa ìwà àìda wọn tó ń mú ìpalára wá
Ìdáríjì NI:
- kíkojú àìda tí a ṣe síwa
- níní ìdámọ̀ irú èrò tó ń jẹyọ lọ́kàn wa
- níní ìpinnu láti má yan odì pẹ̀lú ẹnìkejì wa
- jíjọ̀wọ́ ìkẹ́dùn-ara-ẹni àti ìfẹ́ láti gbẹ̀san
Lákọ̀ọ́kọ́ àti ṣáájú ohun gbogbo ìpinnu ni ìdáríjì jẹ́, kìí ṣe ìmọ̀lára lásán.
- ìṣísẹ̀ onípele ni ìdáríjì -- lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa nílò láti yan ìdáríjì (nígbà mìíràn lójojúmọ́). Bí a ti ńṣe èyí, àwọn ìrántí nípa ìpalára náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní d'ohun ìgbàgbé díẹ̀ díẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kìí wáyé fúnra rẹ̀. Ìrètí wa ni wípé o máa ṣàwárí àwọn ìhà, ìlànà àti àṣà tí o nílò láti sọ ìgbéyàwó di èyí tó ní àlàáfíà tó sì nípọn fún gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí ni a fà yọ látinú ìwée Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó Ṣáájú Ìgbéyàwó tí a tọwọ́ọ Nicky àti Sila Lee kọ, àwọn olùkọ̀wé tó kọ Ìwé Ìgbéyàwó Náà.
More