Wá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀Àpẹrẹ

Seek God Through It

Ọjọ́ 8 nínú 10

Àlááfíà Ọlọ́run jẹ́ ìlérí, gbogbo ìlérí Ọlọ́run ní ó sì ní ìlànà tí ó so pọ̀ mọ́ wọn. À ní láti kọ́ ara wa kí a máṣe ṣe àníyàn. Bíbélì mú ẹnu ba ǹǹkan méjì pàtàkì nípa àlááfíà. Ó wípé: Àlááfíà tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ (Fílípì 4:7) àti àlááfíà pípé (Àìsáyà 26:3).

Bí a bá ń ka àwọn ẹsẹ ìgbaniníyànjú yìí láì ní òye bí a ṣe lè gbé ìgbé-ayé rẹ̀, a ó padà ní kíá sí ohun tí a mọ̀: ṣíṣe ànìyàn.

Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé kí a máṣe ṣe ànìyàn tàbí ní àkókáyà nípa ohunkóhun. Ní àwùjọ ètò-ìlera ọpọlọ tí òde òní, ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè jọ pé kò bá ọ̣gbọ́n mu tàbí pé kò bá ìgbà mu mọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, nínú ohun gbogbo. Kìí ṣe nínú ohun díẹ, ṣùgbọ́n ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ̀ máa fi àwọn ìbéérè yín hàn fún Ọlọ́run. (Fílípì 4:6 YBCV)

Ní ìgbà tí a bá ṣe ohun tí Ìwé-mímọ́ sọ fún wa nìkan ni àlááfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo ọpọlọ wa lọ, yíó ṣọ́ ọkàn àti èrò wa nínú Krístì Jésù.

Ga jù, ní èdè Gíríkì, túmọ̀ sí láti tayọ àti láti lọ rékọjá. Èyí túmọ̀ sí pé àlááfíà tí Ọlọ́run ń pèsè tayọ òye wa. Ó túmọ̀ sí pé àlááfíà Rẹ̀, tí Òun nìkàn lè fúnni, kò bá ọgbọ́n ènìyàn tàbí ọgbọ́n ẹran-ara mu. Kìí ṣe ìyẹn nìkan, ṣúgbọ́n àlááfíà Rẹ̀ ń ṣọ́—bíi ògiri-ina tàbí ètò adènà-àtakò ṣe jẹ́ sí ẹ̀rọ kọ̀mpútà—ọkàn, àti èrò wa nínú Krístì Jésù. Àlááfíà Rẹ̀ á dènà àtakò láti inú ayé yìí tí ó ń gbìyànjú láti so wá ní orí kọ́.

Ọ̀nà kan ṣoṣo láti ṣe àmúlò ìlérí yìí ni nípa ìgbàgbọ́ pé ní ìgbà tí a bá gba àdúrà tí a sì kó gbogbo àníyàn wa wá sí iwájú Jésù, Ọlọ́run kò kàn gbọ́ wa nìkan ṣùgbọ́n yíó tún pèsè ìrọ̀rùn pẹ̀lú àlááfíà Rẹ̀ tí ó ga jù tí ó sì kọjá òye.

Ọjọ́ 8:

  • Ṣe àṣàrò lórí Àlááfíà Rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Seek God Through It

Ìrẹ̀wẹ̀sì. Àníyàn. Àwọn okùnfà àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ro ni lára máa ń ní ipa tí ó ní agbára lórí ọpọlọ, ìmọ̀lára àtì ìgbé-ayé ẹ̀mí wa. Ní àwọn àkókò yìí, wíwá Ọlọ́run á dàbíi pé ó ṣòro tí kò sì já mọ́ ǹǹkan kan. Èròńgbà ètò kíkà yìí, "Wíwá Ọlọ́run Láàrin Rẹ̀" ni láti gbà ọ́ ní ìyànjú àti láti kọ́ ọ ní ọ̀nà tí o fi lè ṣe ìtara níwájú Ọlọ́run, kí o ba lè ní àlàáfíà Ọlọ́run nínú irú ipòkípò tí o lè wà.

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ Brionna Nijah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, Jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.brionnanijah.com/