Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ìgbé Ayé Tí A Yípadà: Èrèdí Rẹ̀Àpẹrẹ

Living Changed: Purpose

Ọjọ́ 1 nínú 5

A Ṣẹ̀dá Rẹ fún Èrèdí Kan



Ẹni kọ̀ọ̀kan wa ni a dá fún èrèdí kan gbógì làti mú ṣẹ nínú ayé yìí. Bí a bá ti ẹ̀ pinnu láti má kọ ibi ara síi, tàbí a kò tilẹ̀ lóye rẹ̀, Ọlọ́run ṣe ẹ̀dá ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú abímọ́ tó yàtọ̀ ní ọ̀nà àrà tí Ó fẹ́ kí á lò láti fi mú kí Ìjọ Rẹ̀ dàgbà. Adúpé lọ́dọ̀ Ọlọ́run tó fi àwọn àmì sí ọkàn wa, tí ó ń ti ipasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tọwa láti ṣe àwárí èrèdí wa.



Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, a ní àwọn nǹkan kannka tí à ń fi ojú inú wò. À ń ṣe ẹ̀dà irú fẹ́ ènìyàn àti ayé nibiti à ti rí ara wa bíi ẹni tó ní ipá láti ṣe ohunkóhun. Kòsí ibi tí àyè kò gbà dé, à fi ọ̀run! A ò tíì mọ ẹ̀rù tàbí kí wọ́n sọ fún wa pé oun kan kò ṣe é ṣe. A ò tíì ní ìdádúró láti ipasẹ̀ àwọn ìrírí ayé tó nira tàbí kí á ní àròkàn nítorí ipò tí a bá ara wa. A ní ìdánilójú nínú ara wa a sì ní òmìnira láti mú àlá wa ṣe.



Mo leè rántí àkókò eré níwájú ìta nínú aṣọ oorun, tòkè-tilẹ̀, ẹ̀yà àwọn akíkanjú-agbanilà. Mo jẹ́ Obìnrin Àràmọ̀ndà, tí ń ģba ayé là lọ́wọ́ ewu! Màá dúró gbọn-in lójú òde pẹ̀lú ọwọ́ mi méjèèjì ní ìbàdí, ní kété tí mo bá kó fìrí rògbòdìyàn, moti fò dé bẹ̀ láti pẹ̀tù si. Pẹ̀lú pé mo ti ṣeré yìí láti àárọ̀, eré yìí kìí sú mi.



Nígbàtí mo dàgbà si, ó yà mí lẹ́nu ìdí tí mo ṣe ní àwọn èròńgbà yẹn nígbà tí mo wà ní ọmọdé. Ó wá hàn sí mi pé pẹ̀lú jíjẹ́ ọmọdé, mo fẹ́ràn láti ran àwọn tí kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Gẹ́gẹ́ bíi olùṣọ́ àgùntàn, oun tí mò ún ṣe gẹ́lẹ́ lónìí nìyí. Mò ń ṣiṣẹ́ láì sinmi láti fa àwọn ènìyàn yọ kúrò lẹ́nu ẹnu ọ̀nà ọ̀run àpáàdì nípa mímú wọn lọ sọ́dọ̀ Olùgbàlà. Mo mọ pé Ọlọ́run dá mi sáyé láti je ìrànwọ́ fún ìgbàlà àwọn ènìyàn. Ó ti fi ìfẹ́ yìí sínú mi láti ìbẹ̀rẹ̀.



Bóyá o kò tilẹ̀ fẹ́ jẹ́ akíkanjú-agbanilà. Dípò bẹ́ẹ̀, ìwọ ma ń kó àwọn bèbí rẹ jọ lá wọlé sùn lálaalẹ́, tàbí ìwọ ti ẹ̀ ńkọ́ àwọn ẹranko tí a fi tìmù tìmù ṣe jọ láti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bóyá ìwọ ti ẹ̀ ń ṣe bí oníṣègùn, aka ìròyìn, tàbí ò ún lọ láti ṣàwárí ayé tuntun. Ala ọjọ́ ọ̀la yóò wù tí o ti lá ni ọmọdé, wọn kò wọ ọkàn rẹ lásán. Ọlọ́run ló fi wọ́n síbẹ̀ fún èrèdí kan. Ó ṣeéṣẹ kí àwọn ènìyàn tí sọ fún ọ pé kí o gbàgbé wọn bí àlá lásán, ṣùgbọ́n wọ́n wà síbẹ̀—a ti hun wọ́n pọ̀ bí aṣọ tó sọ ọ́ di oun tí o jẹ́.



Tí o kò bá mọ à mọ̀ dájú èrèdí Ọlọ́run fún ọ, wò sẹ́yìn àwọn àlá rẹ. Ṣe àṣàrò àwọn oun tó ún mú ọ yọ omi lójú, oun tó un fa okùn ọkàn rẹ, oun tó ún jí ọkàn rẹ sílẹ̀, oun tí ó un rú ìbínú òdodo láyà rẹ. Ó fi àwọn nkan yìí sínú rẹ Ó sì gba ọ̀nà àràbarà dá ọ fún èrèdí fún ìwọ nìkan láti mú ṣe.



Ọlọ́run, Ẹ ṣeun tí Ẹ dá mi pẹ̀lú èrèdí gbógì lọ́kàn. Ẹ ṣeun tí Ẹ fi ọkàn tán mi tí Ẹ sì fún mi ní oun gangan tí mo nílò láti mú ìfẹ́ Yín ṣe láyé mi. Ẹ fi hàn mí ìgbónára, ìrètí, ati irúfé tí Ẹ ti fi sí ọkàn mi, kí Ẹ sì fi hàn mí kedere bí màá ṣe lò wọ́n fún ìjọba Rẹ, Ọlọ́run. Ẹ ràn mí lọ́wọ́ láti má a gbé nínú ìfẹ́ Yín kín sì mú ògo bàa Yín nínú oun gbogbo tí mo bá sọ tàbí ṣe. Ní orúkọ Jésù tí Ó ṣeyebíye, amin.


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Living Changed: Purpose

Ǹjẹ́ o ti fìgbà kankan wòye nípa ohun tí Olórun dá ẹ láti ṣe àbí o tí béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ ìdí tí o fi la àwọn ìrírí kán kọjá? A ṣèdá rẹ ní ònà tó yàtọ̀ fún iṣẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí ìwo nìkàn lè ṣe. Bí o kò tilẹ̀ mọ ọ̀nà tí o máa g...

More

A fẹ dúpẹ lọwọ ile-isẹ Changed Women's Ministries fun ipese eto yii. Fun alaye siwaju sii, jọwọ lọsi: https://www.changedokc.com/

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa