Àwọn Ádùrá Tí Ó L'éwuÀpẹrẹ

Dangerous Prayers

Ọjọ́ 6 nínú 7

Rán Mi

Gẹ́gẹ́ bíi olùṣọ́-àgùntàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, mo ti ríi ní àkọ́kọ́ àwọn ìbéèrè ádùrá tímọ́tímọ́ jùlọ ti ẹgbẹẹgbẹrẹ̀run ènìyàn. Ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, ọgọọgọrun àwọn àìní là n gbà nínú ìjọ wa, láti àwọn ìwé ádùrá nínú àwọn ìsìn wa sí àwọn ìpè foonu l'àkókó ọ̀sẹ̀ tàbí àwọn ìbéèrè orí ayélujára tàbí ohun èlò ìjọsìn wa. Nítorí náà, kì yóò yà ọ́ l'ẹ́nu láti mọ̀ wípé gbólóhùn tí mo máa n gbọ́ jùlọ ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, èyí tí ó sì jẹ́ ìdùnnú ọkàn mi láti mú ṣẹ ni: “Àlùfáà, é bá mi gb'àdúrà fún. . .?”

Mo kà á sí ànfààní, ọlá, àti ojúṣe aláyọ̀ láti dáké jẹ́ láti gbé àìní àwọn ènìyàn s'ókè s'íwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, kí n béèrè fún àánú, láti gbé, láti darí, láti pèsè, láti ṣe, láti ṣe iṣẹ́ ìyanu fún àwọn ènìyàn tí mo mọ̀ tí mo sì nífẹ̀ẹ́. Ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, ẹnìkan yíò béèrè pé kí Ọlọ́run wo ẹni tí wọ́n fẹ́ràn sàn nínú ààrun jegun-jegun, ran aladugbo l'ọ́wọ́ láti rí iṣẹ́, tàbí mú ìgbéyàwó tí ó n bàjẹ́ padà s'ípò. Àwọn ọmọ ilé-ìwé á bèèrè ádùrá láti wọlé sí ilé-ìwé tí wọ́n fẹ́, láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti sanwó fún ilé-ìwé náà, tàbí láti díkù ìrora ti ìkọ̀sílẹ̀ àwọn òbí wọn. Àwọn ẹlòmíràn á gb'àdúrà fún ọkọ tàbí aya. Àwọn míràn á bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti dáríji ẹni tí ó ṣe wọ́n ní ìpalára. 

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ìbéèrè yàtọ̀ sí ara wọn, àwọn ènìyàn n béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti ṣe ohùn kan fún wọn tàbí ẹnìkan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́. Ọlọ́run, ràn mí l'ọ́wọ́. Ọlọ́run, ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹnìkan tí mo nífẹ̀ẹ́. Olúwa, mo nílò .... Baba, jọ̀wọ́ se...? 

Ọlọ́run, ṣe nkan fún mi

Jọ̀wọ́ gbọ́ mi...dájúdájú ó yẹ kí a gb'àdúrà ní ọ̀nà yìí. Ó yẹ kí a pe ìwàláàyè Ọlọ́run, agbára Ọlọ́run, àlàáfíà Ọlọ́run láti là'jà nínú ayé wa nígbà gbogbo. Ó yẹ kí a bẹ Ọlọ́run kí ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nítorí wa. Ó yẹ kí a gbé àwọn àyànfẹ wa s'ókè, kí a sì rán ara wa l'étí bí Ọlọ́run ṣe lè gbà ṣiṣẹ́ nínú ayé wọn. Ó yẹ kí a wá Olúwa fún gbogbo àwọn àìní wa.

Ṣùgbọ́n kò yẹ kí a dá ọwọ́ dúró síbẹ̀

Njẹ́ dípò kí a béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run láti kàn ṣe nkan fún wa, a gb'àdúrà tí ó l'éwu, ádùrá ìjọ̀wọ́ ara ẹ́nì sí Baba wa ọ̀run?

Tí a bá gb'àdúrà tí ó l'éwu jùlọ nkọ́?

“Rán mi, Olúwa. Lò mí.”

Aisaya gba irú ádùrá yìí; ádùrá ìjọ̀wọ́ ailopin ní iwájú Ọlọ́run. Wòlíì Májẹ̀mú Láíláí yìí tún sọ ti alabapade rẹ̀ pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ nígbà tí Ọlọ́run bèèrè pé, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?” (Aisaya 6:8a) Àti láì sì mọ àwọn àlàyé, láì mọ ìgbà tàbí ibo, Aisaya gb'àdúrà ìyàlẹ́nu àti èyí tíí yí ayé padà yìí: “Èmi nìyí, rán mi.” (Aisaya 6:8b).

Ṣe àkíyèsí wípé Aisaya kò bèèrè fún àlàyé kankan. Kò béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run ibi tí ó n lọ. Tàbí ìgbà. Tàbí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Èyí ni ìdí tí ádùrá yìí lè fi dà bíi wípé ó l'éwu. “Ọlọ́run, rán mi. Lò mi. Mí ò béèrè àlàyé. Mí ò nílò láti mọ àwọn ànfàní inú è. Tàbí tí yóò bá r'ọrùn. Tàbí bóyá mo máa gbádùn ẹ̀. Nítorí ẹni tí ìwọ jẹ—Ọlọ́run mi, Ọba mi, Olugbala mi—mo gbẹ́kẹ̀lé ọ. Nítorí ìwọ jẹ́ ọba lórí gbogbo àgbáyé, mo jọ̀wọ́ ìfẹ́ mi fún ọ, gbogbo ẹyà mi. Mú ọkàn mi, ojú mi, ẹnu mi, etí mi, àyà mi, ọwọ́ mi, àti ẹsẹ̀ mi, kí o sì tọ́ mi sí ìfẹ́ rẹ. Mo gbẹ́kẹ̀lé o. Ọlọ́run, ìdáhùn mi ni bẹ́ẹ̀ni. Báyìí kíni ìbéèrè náà?”

F'ojú inú wo tí o bá gb'àdúrà ní ọ̀nà yii. Ṣé àwọn ádùrá tí kò l'éwu sú ọ? Ṣé ó sú ọ láti gbé fún àwọn nkan tí kò ṣe pàtàkì? Ṣé o kęgàn ìgbé ayé Kristiẹniti tí kò dé'nú, tí kò gbóná? T'ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, gb'àdúrà tí ó l'éwu náà.

Èmi nìyí, Olúwa.

Rán mi.

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Dangerous Prayers

Ṣé lílo ìgbàgbọ́ òní jẹ̀nlẹ́ńkẹ́ ti sú ọ? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ṣetán láti dojúkọ àwọn ìbẹ̀rù rẹ, láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti tú agbára rẹ sílẹ̀? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí tí a mú jáde láti inú ìwe Alufa ilé ìjọ́siǹ Life.Church Craig Groeschel, Àwọn Àdúrà Tí Ó Léwu, pè ọ níjà láti gbàdúrà tó léwu—nítorí títẹ̀lé Jésù kò jámọ́ ìrìn-àjò aláìléwu.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àlùfáà Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/