Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Irin-ìdáàbòbò: Yíyẹra fún Àbámọ̀ ní Ìgbésí-ayé RẹÀpẹrẹ

Guardrails: Avoiding Regrets In Your Life

Ọjọ́ 1 nínú 5

Bí kò ti sẹ́ni tó ma mọ̀ọ́mọ̀ ba ọkọ̀ọ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ jẹ́ ni kò ti sẹ́ni tí ó ma fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ bayé ara rẹ̀ jẹ́. Lójúu pópó, àwọn Irin-ìdáàbòbò wà láti dẹ́kun àwọn tó bá fẹ́ mórí wogbó láìrò tẹ́lẹ̀. Báwoni ìbáti dùntó tí irú Irin-ìdáàbòbò bá wà nínú ìgbésí-ayé wá bí ati se àpèjúwe yìí?



Ọ̀pọ̀ nínú àwọn àbámọ̀ wa tó lágbára jù ni aò bá ti yẹra fún tàbí dínkù ká ní a ní Irin-ìdáàbòbò tara ẹni fún owó wa, ìbárẹ́, bí a ti ń ṣe ìdájọ́, àti ẹ̀dùn-ọkàn.



Irin-ìdáàbòbò ara ẹni nííṣe pẹ̀lú gbèdéke ìhùwàsí wa àti ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí-okàn. Wọ́n jẹ́ ìlànà tí oti làálẹ̀ fún araà rẹ láti máa ta ẹ̀rí-ọkàn rẹ jí lóòrè-kóòrè. Àfi bíi Irin-ìdáàbòbò ojú pópó, àwọn ipele tí àtúnṣe ṣì ti rọrùn ni a máa ń gbé wọn sí. Kotó fi ọwọ́ọ̀ rẹ ba iṣẹ́-ààyò rẹ jẹ́, Irin-ìdáàbòbò kan yóò ti ta ọ́ lólobó wípé ewu ńbẹ lóko. Kí ó tó sọ ọ̀rọ̀ tí o kò ní lè kójẹ, Irin-ìdáàbòbò yìí ni yóò ti taọ́ lólobó láti ṣọ́ ọ̀rọ̀ enuù rẹ.



Bí a ti ńfi Irin-ìdáàbòbò tiwa sípò ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ń fún wa l'ámọ̀ràn wípé: "Ẹ máa ṣe àkíyèsí bí ẹ ti ńgbé ìgbésí-ayé yín—bí ọlọ́gbọ́n ẹ má sì ṣe bí òmùgọ . . ."



Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ (bóyá ìwọ alára ti ní ìrírí rẹ̀) wípé o lè lọ sẹ́wọ̀n láì rú òfin. Ètò ìṣúná rẹ le dẹnukọlẹ̀ láì ná ìnákúnàá. O lè ba ìbárẹ́ jẹ́ láì ṣe ohunkóhun tó fara jọ ẹ̀ṣẹ̀.



A kò ṣe ìṣẹ̀dá Irin-ìdáàbòbò láti kọ́wa ni ǹkan tótọ́ àti ìdàkejì rẹ̀. Wọ́n wá níbẹ̀ láti kọ́ọ nípa ọgbọ́n



Nítorí náà, ìbéèrè tí a máa múlò fún owó wa, ìbárẹ́, ìdájọ́, àti àwọn ẹ̀dùn-ọkàn nínú àwọn ọjọ́ mélòó kan wọ̀nyí: Ní ìrònú nípa àwọn ìrírí mi, àwọn ǹkan tí mò ń làkọjá lọ́wọ́lọ́wọ́, àti àwọn ìrètí ọjọ́-iwájú, kíni ǹkan tó mọ́gbọ́n dání láti ṣe?



Nínú ìgbéyàwó rẹ . . . nínú iṣẹ́-ààyò rẹ . . . nígbà tobá nílò láti ṣe ìpinnu nípa ibi tí o máa gbé tàbí bí o ti ma lo àkókò rẹ . . . kíni ǹkan to mọ́gbọ́n dání láti ṣe?



Báwoni ìbéèrè yìí ìbáti yí àwọn ǹkan toti yàn sẹ́yìn padà tàbi àwọn ipò àtijọ́ tí o fa àbámọ̀ fún ọ jùlọ? Ọ̀nà wo ni èyí ti lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Tóbá jẹ́ bèbè kòtò ni ìwọ ti ń rìn, àkókò tó láti lo Irin-ìdáàbòbò. 


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Guardrails: Avoiding Regrets In Your Life

A máa fi irin í dáàbò ojú pópó síbè fún ààbò ọkọ̀ kí wọn má bàa yapa sì ibi tí ó lewu tàbí ibi tí kò yẹ kí wọn rìn sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni a kì í rí wọn títí ao fi nílò wọn - nígbà náà, a ó ṣọpé pe wọn wa níbè. Báwo ni ìb...

More

A fé dúpé lówó North Point Ministries àti Andy Stanley fun ipèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.anthology.study/anthology-app

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa