Àwọn Ìṣé ÌrònúpìwàdàÀpẹrẹ

Ọ̀nà wo ni ò ń tọ̀? Ìbéèrè yìí ni Jésù ń bèèrè ní Luku 13:1-8. Ṣé ọ́nà tí ó tọ́ ni tàbí èyí tí kò tọ́? Ọ̀nà tí ó tọ́ yóò já sí iyè àìnípẹ̀kun, nígbà tí èyí tí kò tọ́ yóò já sí ìparun. Ọ̀rọ̀ Jésù rọrùn: ohun tí o nílò láti ṣe ni kí o ronú pìwàdà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kí o lè ní iyè titun. Tí o kò bá ronúpìwàdà, wà á ṣègbé. Kìí ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti gé wa sọnù, dípò bẹ́ẹ̀ Ó ní ìfẹ́ wa ó sì wù Ú kí á so èso. Irú èso wo ni ò ń so lọ́wọ́lọ́wọ́? Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo ni o nílò láti kọ̀ sílẹ̀ kí o lè bẹ̀rẹ̀ síí so irú èso tí ó wu Ọlọ́run?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ìrònúpìwàdà jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó ṣe kókó tí à ń gbé láti mọ Krístì ní Olùgbàlà wa. Ìrònúpìwàdà ni ojúṣe wa, Ìdáríjì sì ni èsì Ọlọ́run sí wa láti inú ìfẹ́ pípé tí ó ní sí wa. Lásìkò ètò ọlọ́jọ́ márùún yìí, wàá gba bíbélì kíkà ojojúmọ́ àti àmúlò ní ṣókí tí a gbékalẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye síi nípa ìwúlò Ìrònúpìwàdà nínú ìrìn wa pẹ̀lú Krístì. Fún àwọn ètò míràn, ṣe àyẹ̀wò www.finds.life.church
More
We would like to thank Life.Church for providing this plan. For more information, please visit: www.life.church