Rom 11:17-24

Rom 11:17-24 Yoruba Bible (YCE)

A gé díẹ̀ ninu àwọn ẹ̀ka igi olifi inú oko kúrò, a wá lọ́ ẹ̀ka igi olifi inú tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́ dípò rẹ̀. Ẹ̀yin, tí ẹ kì í ṣe Juu, wá dàbí ẹ̀ka igi olifi tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́. Ẹ wá jọ ń rí oúnjẹ ati agbára láti ibìkan náà pẹlu àwọn Juu, tí ó jẹ́ igi olifi inú oko. Nítorí náà, má ṣe fọ́nnu bí ẹni pé o sàn ju àwọn ẹ̀ka ti àkọ́kọ́ lọ. Tí o bá ń fọ́nnu, ranti pé kì í ṣe ìwọ ni ò ń gbé gbòǹgbò ró. Ìwọ yóo wá wí pé, “Gígé ni a gé àwọn ẹ̀ka kúrò kí á lè fi mí rọ́pò wọn.” Lóòótọ́ ni. A gé wọn kúrò nítorí wọn kò gbàgbọ́, nípa igbagbọ ni ìwọ náà fi wà ní ipò rẹ. Mú èrò ìgbéraga kúrò lọ́kàn rẹ, kí o sì ní ọkàn ìbẹ̀rù. Nítorí bí Ọlọrun kò bá dá àwọn tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí, kò ní dá ìwọ náà sí. Nítorí náà ṣe akiyesi ìyọ́nú Ọlọrun ati ìrorò rẹ̀. Ó rorò sí àwọn tí ó kùnà. Yóo yọ́nú sí ọ, tí o bá farabalẹ̀ gba ìyọ́nú rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo gé ìwọ náà kúrò pẹlu. Àwọn Juu tí a gé kúrò yóo tún bọ́ sí ipò wọn pada, bí wọn bá kọ ọ̀nà aigbagbọ sílẹ̀. Ọlọrun lágbára láti tún lọ́ wọn pada sí ibi tí ó ti gé wọn. Ìwọ tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi olifi tí ó la ilẹ̀ hù ninu ìgbẹ́, tí a lọ́ mọ́ ara igi olifi inú oko, tí ẹ̀dá wọn yàtọ̀ sí ara wọn, báwo ni yóo ti rọrùn tó láti tún lọ́ àwọn tí ó jẹ́ ara igi olifi inú oko tẹ́lẹ̀ mọ́ ara igi tí a ti gé wọn kúrò!

Rom 11:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n bí a bá ya nínú àwọn ẹ̀ka kúrò, tí a sì lọ́ ìwọ, tí í ṣe igi òróró igbó sára wọn, tí ìwọ sì ń bá wọn pín nínú gbòǹgbò àti ọ̀rá igi olifi náà, Má ṣe ṣe féfé sí àwọn ẹ̀ka igi náà. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ṣe féfé, ìwọ kọ́ ni ó rù gbòǹgbò, ṣùgbọ́n gbòǹgbò ni ó rù ìwọ. Ǹjẹ́ ìwọ ó wí pé, “A ti fa àwọn ẹ̀ka náà ya, nítorí kí a lè lọ́ mi sínú rẹ̀.” Ó dára; nítorí àìgbàgbọ́ ni a ṣe fà wọn ya kúrò, ìwọ sì dúró nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Má ṣe gbé ara rẹ ga, ṣùgbọ́n bẹ̀rù. Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá ẹ̀ka-ìyẹ́ka sí, kíyèsára kí ó má ṣe ṣe àìdá ìwọ náà sí. Nítorí náà wo oore àti ìkáàánú Ọlọ́run; lórí àwọn tí ó ṣubú, ìkáàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, oore, bi ìwọ bá dúró nínú oore rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò. Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀. Nítorí bí a bá ti ké ìwọ kúrò lára igi òróró igbó nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì lọ́ ìwọ sínú igi òróró rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòó mélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi òróró wọn?