Rom 11:17-24

Rom 11:17-24 YBCV

Ṣugbọn bi a ba yà ninu awọn ẹ̀ka kuro, ti a si lọ́ iwọ, ti iṣe igi oróro igbẹ́ sara wọn, ti iwọ si mba wọn pín ninu gbòngbo ati ọra igi oróro na; Máṣe ṣe fefé si awọn ẹ̀ka na. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe fefé, iwọ kọ́ li o rù gbòngbo, ṣugbọn gbòngbo li o rù iwọ. Njẹ iwọ o wipe, A ti fà awọn ẹ̀ka na ya, nitori ki a le lọ́ mi sinu rẹ̀. O dara; nitori aigbagbọ́ li a ṣe fà wọn ya kuro, iwọ si duro nipa igbagbọ́ rẹ. Máṣe gbé ara rẹ ga, ṣugbọn bẹ̀ru: Nitori bi Ọlọrun kò ba da ẹ̀ka-iyẹka si, kiyesara ki o máṣe alaida iwọ na si. Nitorina wo ore ati ikannu Ọlọrun: lori awọn ti o ṣubu, ikannu; ṣugbọn lori iwọ, ore, bi iwọ ba duro ninu ore rẹ̀: ki a má ba ke iwọ na kuro. Ati awọn pẹlu, bi nwọn kò ba joko sinu aigbagbọ́, a o lọ́ wọn sinu rẹ̀: nitori Ọlọrun le tún wọn lọ́ sinu rẹ̀. Nitori bi a ti ke iwọ kuro lara igi oróro igbẹ́ nipa ẹda, ti a si lọ́ iwọ sinu igi oróro rere lodi si ti ẹda: melomelo li a o lọ́ awọn wọnyi, ti iṣe ẹka-iyẹka sara igi oróro wọn?