O. Daf 63:2-4 - Compare All Versions

O. Daf 63:2-4 YBCV (Bibeli Mimọ)

Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ. Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ. Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ.

O. Daf 63:2-4 YCE (Yoruba Bible)

Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ, mo ti rí agbára ati ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ, n óo máa yìn ọ́. N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi; n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ.

O. Daf 63:2-4 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ. Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.