O. Daf 111:1-6
O. Daf 111:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ ma yìn Oluwa. Emi o ma yìn Oluwa tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia. Iṣẹ Oluwa tobi, iwa-kiri ni fun gbogbo awọn ti o ni ifẹ rẹ̀ ninu. Iṣe rẹ̀ li ọlá on ogo, ododo rẹ̀ si duro lailai. O ṣe iṣẹ iyanu rẹ̀ ni iranti: olore-ọfẹ́ li Oluwa o si kún fun ãnu. O ti fi onjẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀: yio ranti majẹmu rẹ̀ lailai. O ti fi iṣẹ agbara rẹ̀ hàn awọn enia rẹ̀, ki o le fun wọn ni ilẹ-ini awọn keferi.
O. Daf 111:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ yin OLUWA! N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn, láàrin àwọn olódodo, ati ní àwùjọ àwọn eniyan. Iṣẹ́ OLUWA tóbi, àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri. Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo, òdodo rẹ̀ sì wà títí lae. OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀, a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae. Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀, nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
O. Daf 111:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa yin OLúWA. Èmi yóò máa yin OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn. Iṣẹ́ OLúWA tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo: àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé. Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí: OLúWA ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú. Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀: òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀. Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní