ORIN DAFIDI 111
111
Yin OLUWA
1Ẹ yin OLUWA!
N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn,
láàrin àwọn olódodo,
ati ní àwùjọ àwọn eniyan.
2Iṣẹ́ OLUWA tóbi,
àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri.
3Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo,
òdodo rẹ̀ sì wà títí lae.
4OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,
olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀.
5A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀,
a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae.
6Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀,
nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
7Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà,
gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú.
8Wọ́n wà títí lae ati laelae,
ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin.
9Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀,
ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae,
mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀.
10Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,
gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé.
Títí lae ni ìyìn rẹ̀.#Job 28:28; Owe 1:7; 9:10
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 111: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010