Owe 7:21-27
Owe 7:21-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀rọ rẹ̀ daradara li o fi mu u fẹ, ipọnni ète rẹ̀ li o fi ṣẹ́ ẹ li apa. On si tọ̀ ọ lọ lẹsẹkanna bi malu ti nlọ si ibupa, tabi bi aṣiwere ti nlọ si ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́. Titi ọfà fi gún u li ẹ̀dọ̀; bi ẹiyẹ ti nyara bọ sinu okùn, ti kò si mọ̀ pe fun ẹmi on ni. Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi. Máṣe jẹ ki aiya rẹ̀ ki o tẹ̀ si ọ̀na rẹ̀, máṣe ṣina lọ si ipa-ọ̀na rẹ̀. Nitori ọ̀pọlọpọ enia li o ṣá lulẹ; nitõtọ ọ̀pọlọpọ alagbara enia li a ti ọwọ rẹ̀ pa. Ile rẹ̀ li ọ̀na ọrun-apadi, ti nsọkalẹ lọ si iyẹwu ikú.
Owe 7:21-27 Yoruba Bible (YCE)
Ó rọ̀ ọ́ pẹlu ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, ó fi ọ̀rọ̀ dídùn mú un. Lẹsẹkẹsẹ, ọmọkunrin náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀lé e, bíi mààlúù tí wọn ń fà lọ pa, tabi bí àgbọ̀nrín tí ó tẹsẹ̀ bọ tàkúté, títí tí ọfà fi wọ̀ ọ́ ninu bí ẹyẹ tí ń yára bọ́ sinu okùn, láì mọ̀ pé ó lè ṣe ikú pa òun. Nisinsinyii, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ farabalẹ̀ gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín lọ sọ́dọ̀ irú obinrin bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣèèṣì yà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti sọ di ẹni ilẹ̀, ọpọlọpọ àwọn alágbára ni ó ti ṣe ikú pa. Ọ̀nà isà òkú tààrà ni ilé rẹ̀, ilé rẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá sí ìparun.
Owe 7:21-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn. Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibùpa, tàbí bí (aṣiwèrè) àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́. Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀ Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.