Owe 6:6-15
Owe 6:6-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rẹ̀ ki iwọ ki o si gbọ́n: Ti kò ni onidajọ, alabojuto, tabi alakoso. Ti npese onjẹ rẹ̀ ni igba-ẹ̀run, ti o si nkó onjẹ rẹ̀ jọ ni ìgba ikore. Ọlẹ, iwọ o ti sùn pẹ to? nigbawo ni iwọ o dide kuro ninu orun rẹ? Orun diẹ si i, õgbe diẹ si i, ikawọkòpọ lati sùn diẹ: Bẹ̃ni òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn àjo, ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun. Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke. O nṣẹju rẹ̀, o nfi ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ, o nfi ika rẹ̀ ṣe ajuwe; Arekereke mbẹ li aiya rẹ̀, o humọ ìwa-ika nigbagbogbo; o ndá ija silẹ. Nitorina ni ipọnju rẹ̀ yio de si i lojiji; ojiji ni yio ṣẹ́ laini atunṣe.
Owe 6:6-15 Yoruba Bible (YCE)
Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ, ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n. Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn; a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè. O óo ti sùn pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ? Ìgbà wo ni o óo tají lójú oorun? Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi, yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni. Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri, a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè, bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe. Ó ń fi inú burúkú pète ibi, ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀, nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì, yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.
Owe 6:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n! Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba, síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ? Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ? Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀ Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè. Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri, tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò, ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe, tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀. Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn; yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.