Owe 4:23-26 - Compare All Versions
Owe 4:23-26 YBCV (Bibeli Mimọ)
Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye. Mu arekereke kuro lọdọ rẹ, ati ète ẹ̀tan jina rére kuro lọdọ rẹ. Jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ. Ronu ipa-ọ̀na rẹ, gbogbo ọ̀na rẹ ni yio si fi idi mulẹ.
Owe 4:23-26 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́, nítorí òun ni orísun ìyè. Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á. Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.
Owe 4:23-26 YCE (Yoruba Bible)
Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ, nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè. Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán, kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà. Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ, gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là.