Owe 22:7-16
Owe 22:7-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrọ̀ ṣe olori olupọnju, ajigbese si ṣe iranṣẹ fun onigbese. Ẹniti o ba funrugbin ẹ̀ṣẹ, yio ri asan ka: ọpá ibinu rẹ̀ si ti mura tan. Ẹniti o li oju ãnu li a o bukun fun; nitoriti o fi ninu onjẹ rẹ̀ fun olupọnju. Ṣá ẹlẹgàn tì sode, ìja yio si jade; nitõtọ ìja ati ẹ̀gan yio dẹkun. Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀. Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po. Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro. Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀. Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀. Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe.
Owe 22:7-16 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí, ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó. Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú, pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun. Olójú àánú yóo rí ibukun gbà, nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀. Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀, asọ̀ ati èébú yóo sì dópin. Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́, tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́. Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́, ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po. Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta! Yóo pa mí jẹ lójú pópó!” Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá, ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀. Ìwà agídí dì sí ọkàn ọmọde, ṣugbọn pàṣán ìbáwí níí lé e jáde. Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ, tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka.
Owe 22:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà. Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú. Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde; nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun. Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ojú OLúWA pa ìmọ̀ mọ́, ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò. Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde! Yóò pa mí ní ìgboro!” Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni; ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀. Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí; ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.