Owe 20:1-4
Owe 20:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸLẸYA li ọti-waini, alariwo li ọti lile, ẹnikẹni ti a ba fi tanjẹ kò gbọ́n. Ibẹ̀ru ọba dabi igbe kiniun: ẹnikẹni ti o ba mu u binu, o ṣẹ̀ si ọkàn ara rẹ̀. Ọlá ni fun enia lati ṣiwọ kuro ninu ìja: ṣugbọn olukuluku aṣiwère ni ima ja ìja nla. Ọlẹ kò jẹ tu ilẹ nitori otutu; nitorina ni yio fi ma ṣagbe nigba ikore, kì yio si ni nkan.
Owe 20:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹlẹ́yà ni ọtí waini, aláriwo ní ọtí líle, ẹnikẹ́ni tí a bá fi tànjẹ kò gbọ́n. Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu. Nǹkan iyì ni pé kí eniyan máa yẹra fún ìjà, ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan níí máa ń jà. Ọ̀lẹ kì í dáko ní àkókò, nítorí náà, nígbà ìkórè, kò ní rí nǹkankan kó jọ.
Owe 20:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n. Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà. Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.