Owe 2:7-10 - Compare All Versions
Owe 2:7-10 YBCV (Bibeli Mimọ)
O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede. O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́. Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere. Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ
Owe 2:7-10 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé, Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́, àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere. Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.
Owe 2:7-10 YCE (Yoruba Bible)
Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́, ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere. Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára