Owe 2:1-8
Owe 2:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌMỌ mi, bi iwọ ba fẹ igba ọ̀rọ mi, ki iwọ si pa ofin mi mọ́ pẹlu rẹ. Ti iwọ dẹti rẹ silẹ si ọgbọ́n, ti iwọ si fi ọkàn si oye; Ani bi iwọ ba nke tọ̀ ìmọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohùn rẹ soke fun oye; Bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ́; Nigbana ni iwọ o mọ̀ ibẹ̀ru Oluwa, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun. Nitori Oluwa ni ifi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ ati oye ti iwá. O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede. O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́.
Owe 2:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí o sì fi ọkàn sí òye, bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀, tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀, bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka, tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́, nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ. O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun. Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n, ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá. Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́, ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́.
Owe 2:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ, tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye, àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù OLúWA, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run. Nítorí OLúWA ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé, ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.