Owe 2:1-22

Owe 2:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌMỌ mi, bi iwọ ba fẹ igba ọ̀rọ mi, ki iwọ si pa ofin mi mọ́ pẹlu rẹ. Ti iwọ dẹti rẹ silẹ si ọgbọ́n, ti iwọ si fi ọkàn si oye; Ani bi iwọ ba nke tọ̀ ìmọ lẹhin, ti iwọ si gbé ohùn rẹ soke fun oye; Bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀ bi fadaka, ti iwọ si nwá a kiri bi iṣura ti a pamọ́; Nigbana ni iwọ o mọ̀ ibẹ̀ru Oluwa, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun. Nitori Oluwa ni ifi ọgbọ́n funni: lati ẹnu rẹ̀ jade ni ìmọ ati oye ti iwá. O to igbala jọ fun awọn olododo: on li asà fun awọn ti nrìn dede. O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn ayanfẹ rẹ̀ mọ́. Nigbana ni iwọ o mọ̀ ododo, ati idajọ, ati aiṣegbe; ani, gbogbo ipa-ọ̀na rere. Nigbati ọgbọ́n bá wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn mọ ọkàn rẹ; Imoye yio pa ọ mọ́, oye yio si ma ṣọ́ ọ: Lati gbà ọ li ọwọ ẹni-ibi, li ọwọ ọkunrin ti nsọrọ ayidayida; Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun; Ẹniti o yọ̀ ni buburu iṣe, ti o ṣe inu-didùn si ayidàyidà awọn enia buburu; Ọ̀na ẹniti o wọ́, nwọn si ṣe arekereke ni ipa-ọ̀na wọn: Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni; Ẹniti o kọ̀ ọrẹ́ igbà-ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀. Nitoripe ile rẹ̀ tẹ̀ sinu ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ awọn okú. Kò si ẹniti o tọ̀ ọ lọ ti o si tun pada sẹhin, bẹ̃ni nwọn kì idé ipa-ọ̀na ìye. Ki iwọ ki o le ma rin li ọ̀na enia rere, ki iwọ ki o si pa ọ̀na awọn olododo mọ́. Nitoripe ẹni-iduroṣinṣin ni yio joko ni ilẹ na, awọn ti o pé yio si ma wà ninu rẹ̀. Ṣugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro ni ilẹ aiye, ati awọn olurekọja li a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.

Owe 2:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí o sì fi ọkàn sí òye, bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀, tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀, bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka, tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́, nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ. O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun. Nítorí OLUWA níí fún ni ní ọgbọ́n, ẹnu rẹ̀ sì ni òye ati ìmọ̀ ti ń wá. Ó fún àwọn tí wọn dúró ṣinṣin ní ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n, òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ó ń tọ́ wọn sí ìdájọ́ òtítọ́, ó sì ń pa ọ̀nà àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìtumọ̀ òdodo ati ẹ̀tọ́ yóo yé ọ ati àìṣe ojuṣaaju, ati gbogbo ọ̀nà rere. Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára, ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ, òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́, yóo máa gbà ọ́ lọ́wọ́ ibi ṣíṣe, ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn, àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀ tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn; àwọn tí wọn ń yọ̀ ninu ìwà ibi tí wọ́n sì ní inú dídùn sí ìyapa ibi; àwọn tí ọ̀nà wọn wọ́, tí wọ́n kún fún ìwà àrékérekè. A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe, àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀. Ẹni tí ó kọ ọkọ àárọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbàgbé majẹmu Ọlọrun rẹ̀. Ẹni tí ilé rẹ̀ rì sinu ìparun, tí ọ̀nà rẹ̀ sì wà ninu ọ̀fìn isà òkú. Kò sí ẹni tí ó tọ̀ ọ́ lọ, tí ó pada rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tún pada sí ọ̀nà ìyè. Nítorí náà, máa rìn ní ọ̀nà àwọn eniyan rere, sì máa bá àwọn olódodo rìn. Nítorí àwọn tí wọ́n dúró ṣinṣin ni wọn yóo máa gbé ilẹ̀ náà, àwọn olóòótọ́ inú ni yóo máa wà níbẹ̀, ṣugbọn a óo pa ẹni ibi run lórí ilẹ̀ náà, a óo sì fa alárèékérekè tu kúrò níbẹ̀.

Owe 2:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ, tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye, àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù OLúWA, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run. Nítorí OLúWA ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé, ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́, àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere. Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ Ìmòye yóò pa ọ mọ́ òye yóò sì máa ṣọ́ ọ. Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà, ẹni tí ó kúrò ní ọ̀nà ìdúró ṣinṣin láti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn, ẹni tí ó yọ̀ nínú ṣíṣe búburú, tí ó ṣe inú dídùn sí àyídáyidà àwọn ènìyàn ibi, ọ̀nà ẹni tí ó wọ́ tí wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ní ọ̀nà wọn. Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin, àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ, ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀. Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú. Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́. Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.