Num 14:17-18
Num 14:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe, Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin.
Num 14:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà OLUWA, èmi bẹ̀ Ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ pé, ‘OLUWA kì í tètè bínú, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé ji eniyan, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà. A máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.’
Num 14:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé: ‘OLúWA lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’